Oriire nla! Ẹgbẹrun meji oṣiṣẹ gba iwe igbega lẹnu iṣẹ ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, February 20, 2026

Oriire nla! Ẹgbẹrun meji oṣiṣẹ gba iwe igbega lẹnu iṣẹ ni Kwara



Awọn oṣiṣẹ ti ko din ni ẹgbẹrun meji ni wọn gba iwe igbega lẹnu iṣẹ kaakiri ijọba ipinlẹ Kwara.

Igbega ọhun lo jẹ ti ọdun 2024, gẹgẹ bi a ṣe gbọ.

Alaga ileeṣẹ to n ri sọrọ awọn oṣiṣẹ, iyẹn 'State Civil Service Commission, Hajia Habibat Yusuf lo fidi iroyin naa mulẹ niluu Ilọrin laipẹ yii.

Nigba to n sọrọ, Hajia Habibat Yusuf gbe oṣuba kare fun Gomina Abdulrahman Abdulrazaq, lori bo ṣe mu ọrọ igbayegbadun awọn oṣiṣẹ lokunkundun nipinlẹ naa.

O ni ohun iwuri ni bi gomina ṣe buwọ lu iwe igbega awọn oṣiṣẹ fun ọdun 2024.

Gẹgẹ bo ṣe ṣalaye, o ni awọn oṣiṣẹ to le ni ẹgbẹrun meji ni wọn jokoo fun idanwo igbega ati ifọrọwerọ igbega ti ọdun 2024, to si jẹ pe awọn ida mọkandinlọgọrun ni wọn yege.

Hajia Yusuf fidi rẹ mulẹ pe gbogbo awọnt o yege patapata ni wọn ti gba iwe igbega wọn, ti onikaluku wọn si ti bọ si ipele igbega to tọ si wọn, ati pe gbogbo awọn owo oṣu ati ajẹmọnu to ba igbega naa lọ, ni wọn yoo bẹrẹ sii jẹ anfaani rẹ bayii.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI