Eyi lawọn meji ti ileeṣẹ ọlọpaa ranṣẹ pe lori ipo Awujalẹ n'Ijẹbu - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, February 6, 2026

Eyi lawọn meji ti ileeṣẹ ọlọpaa ranṣẹ pe lori ipo Awujalẹ n'Ijẹbu


Ọpọ awọn ọmọ Ijẹbu nipinlẹ Ogun, paapaa awọn to n ba eto yiyan Awujalẹ tuntun lọ lagbaye lo la ẹnu wọn silẹ, ti wọn ko si fẹẹ le pa a de lọjọ Iṣẹgun to kọja yii, nigba ti wọn ri iwe ti ajọ ọlọpaa ipinlẹ naa fi ranṣẹ pe awọn oloye ilẹ Ijẹbu meji kan, lori ẹsun gbigba owo abẹtẹlẹ.

Ninu lẹta meji ọtọọtọ to tẹ AWIKONKO lọwọ ni alẹ ọjọ naa, agba oloṣelu nni, Ọtunba Jimi Lawal, ẹni to tun jẹ Olotu Ifore ati Oloye Rasheed Adeoye Adesanya toun jẹ Olisa ilẹ Ijẹbu ni ọlọpaa sọ pe ki wọn yọju lati sọ tẹnu wọn.

Gẹgẹ bi lẹta naa ti DCP Gbenga Adeoye, ẹni to jẹ igbakeji ọga ọlọpaa Ogun lẹka to n ṣe iwadii ọran, CID, fi ranṣẹ si awọn oloye meji naa, o ni wọn gbọdọ yọju lati ṣalaye lẹkunrẹrẹ lori ẹsun owo abẹtẹlẹ ti wọn n ṣe iwadii rẹ lọwọ.

‘‘Ileeṣẹ ọlọpaa, ẹka to n ri si iwadii ẹsun ọran nipinlẹ yii n ṣiṣẹ iwadii lori ẹsun owo abẹtẹlẹ ati magomago owo, leyi to jẹ pe a nilo lati ṣe iwadii kikun lati ọdọ yin,’’ lẹta naa ti wọn fi ranṣẹ sawọn mejeeji lọtọọtọ sọ bẹẹ.

Ọga ọlọpaa Adeoye sọ pe Ọjọbọ, tii ṣe oni, ọjọ karun, oṣu Keji, ọdun 2026 ni ki awọn mejeeji yọju si wọn ni ileeṣẹ wọn to wa ni Eleweran niluu Abẹokuta, ni deedee agogo owurọ.

‘‘A n fẹ ki ẹ yọju si wa ni ẹka to n ri si iwadii ọran, SCIDto wa ni Eleweran niluu Abẹokuta, ipinlẹ Ogun l’Ọjọbọ, ọjọ karun-un, oṣu Keji, ọdun 2026 ni deedee agogo mẹwaa owurọ fun ifọrọwerọ pẹlu igbakeji ọga ọlọpaa, ẹka ti State Criminal Investigation Department.’’

Siwaju sii ni ọga ọlọpaa naa jẹ ko di mimọ pe o ṣe pataki fun agba oloye naa lati yọju si wọn, lati le ran iṣẹ iwadii wọn lọwọ, ni ibamu pẹlu agbara ọlọpaa, eyi to wa ni abala 214 ninu iwe ofin ilẹ Naijiria, ti ọdun 1999, ati abala kẹrin ninu iwe ofin ọlọpaa ti ọdun 2020.

O ni bi wọn ba nilo lati beere ohunkohun, ki wọn pe ẹrọ ibanisọrọ 08038455857, ati pe wọn ni anfaani lati mu agbẹjọro wọn dani.

‘‘Wiwa yin ṣe pataki lati le ran iṣẹ iwadii wa lọwọ lati le fi idajọ ododo mulẹ. Bi ẹ ba nilo alaye lori ohunkohun, ẹ le pe 08038455857. Ẹ dakun, ẹ tete de, ati pe ẹ mọ daju pe anfaani wa fun un yin lati mu agbẹjọro yin dani.’’

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI