Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun labẹ iṣakoso Ọga Lanre Ogunlọwọ ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ afurasi meji miran ti wọn lọwọ si idigun gba tirela simẹnti Dangote.
Bi ẹ ko ba gbagbe, ọjọ kejilelogun, oṣu Kinni, ọdun yii ni ọlọpaa sọ pe ọwọ tẹ afurasi mẹjọ ti wọn digun gba tirela ọhun pẹlu simẹnti ọgọrun mẹsan.
Ibi ti wọn lọ ja awọn simẹnti naa si la gbọ pe ọwọ palaba pupọ ninu awọn afurasi ọdaran ọhun ti segi nigba naa.
Ṣugbọn ni bayii, nigba to tun n sọ nipa idagbasoke to de ba itẹsiwaju iwadii ọlọpaa, agbẹnusọ wọn, Oluṣeyi Babaṣeyi jẹ ko di mimọ pe ọwọ tun ti tẹ awọn meji miran.
“Ileeṣẹ ọlọpaa tun ti fọwọ ṣikun ofin mu afurasi meji ni ibamu pẹlu iṣẹ iwadii to n lọ lọwọ lori didigun gba tirela simẹnti,” Babaṣeyi sọ bẹẹ ninu atẹjade to fi sita.
“Awọn afurasi naa, John Ṣeun, ẹni ọdun mẹrinlelogun ti wọn tun n pe ni Dagrin ati Ọlanipẹkun Ezekiel, ẹni ọdun marundinlogoji ti wọn tun n pe ni ‘Sharply’.”
Babaṣeyi jẹ ko di mimọ pe awọn afurasi naa ko ipa to jọju ninu idigun gba tirela ọhun to ko ọgọrun mẹsan simẹnti, ti wọn si lọ ta a danu.
O ni ninu iwadii ni awọn afurasi naa ti jẹwọ pe awọn paayan danu lasiko iṣẹ ibi t’awọn ṣe.
Bẹẹ lo tun jẹ ko di mimọ pe iwadii ko tii pari, nitori pe awọn ṣi n ṣiṣẹ lati rọwọ to awọn afurasi yooku ti wọn na papa bora.
No comments:
Post a Comment