Gomina AbdulRazaq gbe igbimọ ẹlẹni meje dide lati ṣe iranlọwọ fawọn to fara kaaṣa nibi ikọlu to waye ni Woro - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, February 6, 2026

Gomina AbdulRazaq gbe igbimọ ẹlẹni meje dide lati ṣe iranlọwọ fawọn to fara kaaṣa nibi ikọlu to waye ni Woro


Bo tilẹ jẹ pe titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni ikọlu to waye niluu Woro, ipinlẹ Kwara ṣi n jẹ fun ọpọ eeyan lagbaye, sibẹ ijọba ti sọ pe iranlọwọ yoo dide fun gbogbo awọn to fara kaaṣa nibẹ.

Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ naa ti buwọlu igbimọ ẹlẹni meje kan lati ṣe iwadii lori awọn ti ikọlu ọhun pa lara, lati le ṣe iranlọwọ to ba yẹ fun wọn.

Ọkan lara awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa tẹlẹri, Ọnarebu Ahmed Kiwosi, ẹni to ṣoju ẹkun Kaiama ni alaga igbimọ ọhun ti gomina buwọlu.

Nigba to n fidi rẹ mulẹ ninu atẹjade ti akọwe iroyin gomina, Ọgbẹni Rafiu Ajakaye fi sita loni ọjọ Ẹti, o ni awọn aṣoju ijọba naa ko gbẹyin ninu igbimọ ọhun.

Lara wọn si ni igbakeji alaga kansu ni Kaiama, Aisha Abubakar Sadiq; Alaaji Abubakar Mora; ati Baalẹ abule Woro, Alaaji Umar Bio Saliu.

Awọn miran ni awọn aṣoju nileeṣẹ to n ri si iṣẹlẹ pajawiri, State Emergency Management Agency (SEMA); Kwara State Social Investment Programme (KWASSIP); ati obinrin kan lati ọfiisi akọwe ijọba ipinlẹ Kwara 

AWIKONKO gbọ pe ọsẹ mẹrin pere ni igbimọ naa nilo lati fi ṣe iwadii lati mọ awọn to fara kaaṣa, ati iranlọwọ ti wọn yoo nilo, to fi mọ awọn ohun miran to ba tun jẹyọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI