Akewejẹ tiluu Aran-Orin nipinlẹ Kwara, Oloye Michael Olayinka Fafoluyi ti gbe oṣuba kare fun alaga ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress nipinlẹ naa, Ọmọọba Sunday Fagbemi lori bo ṣe gba ipo tuntun gẹgẹ bii alaga ẹgbẹ awọn to n ri sọrọ ẹgbẹ oṣelu nipinlẹ naa, iyẹn Inter Party Advisory Council, IPAC .
Fafoluyi tọpọ tun mọ si Solace, ẹni to jẹ amugbalẹgbẹ agba pataki fun Gomina ipinlẹ Kwara lori eto iroyin igbalode lo gbe oṣuba naa ninu atẹjade to fi ki alaga IPAC tuntun ọhun.
Ninu atẹajde ọhun to fi sita lọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii, Akewejẹ Fafoluyi jẹ ko di mimọ pe igi to tọ ni wọn fi sinu iho to tọ, ati pe igbagbọ ati idaniloju wa pe alaga tuntun naa yoo mu iṣọkan ba gbogbo ẹgbẹ oṣelu to wa nipinlẹ naa.
O ṣapejuwe Ọmọọba Fagbemi gẹgẹ bi ẹni to ni ọgbọn ati oye, pẹlu awọn iriri to le fi tukọ ẹgbẹ IPAC, lati mu lọ si ipele giga ti ko wọpọ.
“Agba oloṣelu to ni iriri to pọ nipa ọrọ oṣelu ni Ọmọọba Fagbemi jẹ, o si ti lo iriri rẹ, okun ati agbara, to fi mọ imọ to ni lati fi gbe eto oṣelu awa-ara-wa larugẹ kaakiri ilẹ Naijiria, to si tun jẹ awokọṣe rere fun awọn ọdọ, fun idagbasoke ọjọ iwaju ilẹ yii.
“Irin ajo oṣelu ọjọ pipẹ rẹ nipinlẹ Kwara ti ko ipa to pọ, to si jọju ninu itẹsiwaju oṣelu nipinlẹ naa, ati eto iṣejọba awa-ara-wa," Akewejẹ sọ bẹẹ.

No comments:
Post a Comment