Ijọba ipinlẹ Ogun ṣagbekalẹ yara ikẹkọọ ti imọ-ẹrọ 'AI' - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Wednesday, February 11, 2026

Ijọba ipinlẹ Ogun ṣagbekalẹ yara ikẹkọọ ti imọ-ẹrọ 'AI'


Ijọba ipinlẹ Ogun labẹ iṣakoso Gomina Dapọ Abiọdun ti buwọ lu agbekalẹ yara ikẹkọọ ti imọ ẹrọ AI, oni biliọnu kan naira, eyi ti wọn fẹẹ kọ si ile-ẹkọ girama ti Rẹmọ, iyẹn Remo Secondary School niluu Ṣagamu.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, yara ikẹkọọ naa ni yoo gba to ọgọrun mẹsan eeyan lẹẹkan ṣoṣo lati kẹkọọ lẹẹkan naa.

Gomina Abiọdun lo sọrọ yii nibi eto ayẹyẹ idasilẹ ọgọrin ọdun ti wọn da ile-ẹkọ naa silẹ, eyi to waye laipẹ yii.

Nigba to n sọrọ, gomina sọ pe agbekalẹ naa yoo mu idagbasoke ba eto ẹkọ nipinlẹ naa nipa imọ ẹrọ igbalode.

Lara awọn to wa nibẹ lọjọ naa ni iyawo gomina, Arabinrin Bamidele Abiodun; Akarigbo tilẹ Remo, Ọba Babatunde Ajayi; Alakoso ileeṣẹ Adron Homes, Aarẹ Adetola Emmanuelking.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI