Ibanujẹ lo maa n jẹ fun mi, bi mo ba ri awọn ọmọdebinrin to yẹ ko wa nile-ẹkọ, ti wọn n kiri ata - Olori Fashola-MacGregor - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, February 12, 2026

Ibanujẹ lo maa n jẹ fun mi, bi mo ba ri awọn ọmọdebinrin to yẹ ko wa nile-ẹkọ, ti wọn n kiri ata - Olori Fashola-MacGregor

Olori laafin Olu Orile-Ilawọ nipinlẹ Ogun, Olori Ọmọlara Fashola-MacGregor ti sọ pe ẹdun ọkan lo maa n jẹ foun nigba toun ba n foju ri awọn ọmọdebinrin to yẹ ko wa nile-ẹkọ, ti wọn kiri ata, ewedu ati awọn ohun ti ko yẹ kaakiri igboro.

Aya Ọba Alexandar Oluṣẹgun MacGregor sọ pe ọpọ igba loun ti bu ṣekun nigba toun ba gbọ pe eto ẹkọ awọn ọmọdebinrin to yẹ ki wọn jẹ ogo ọjọ iwaju ilẹ Naijiria duro lojiji, nitori oyun airo tẹlẹ ti wọn lọ gbe.

Olori Fashola-MacGregor lo sọrọ naa niluu Abẹokuta, nibi akanṣe eto idanilẹkọọ to ṣagbekalẹ rẹ ninu aafin, nibi ti awọn akẹkọọbinrin ti ko din ni igba ti peju lati kẹkọọ.

Eto ọhun ti ajọ VWETA CHADWICK EMPOWERMENT FOUNDATION, eyi ti wọn tun n pe ni Project Asha lati ilu Abuja ṣagbatẹru rẹ, lo waye l’Ọjọru, ọsẹ yii ni aafin Orile-Ilawọ to wa niluu Abẹokuta.

Nigba to n sọrọ, Olori naa sọ pe ohun to yẹ ki awọn ọmọbinrin kọkọ gbọdọ mọ ni pe ni kete ti wọn ba ti kọkọ ri nnkan oṣu wọn, ki wọn nigbagbọ pe oyun ti le duro si wọn lara, ti wọn si gbọdọ sa fun gbogbo ọkunrin nipa ibalopọ.

O ni bo tilẹ jẹ pe oyun tabi ọmọ bibi kii ṣe arun tabi aisan, ṣugbọn to sọ pe akoba nla ni yoo jẹ fun awọn ọmọde niwọn igba ti ko ba tii to asiko to yẹ fun wọn.

“O maa n ba mi lọkan jẹ nigba ti mo ba n ri awọn ọmọde ti ko tii balaga lati maa pọn ọmọ kaakiri, awọn ọmọ to yẹ ki wọn wa ṣi wa nile-ẹkọ ni wọn ti wa di alabiyamọ, kii ṣe ohun to bojumu rara, a si nilo lati tete dẹkun rẹ.

“O dara fun obinrin lati tete bimọ, ṣugbọn kii ṣe pe ki obinrin bimọ lai tii pari eto ẹkọ rẹ. Eto ẹkọ maa duro ni bi ọmọbinrin ba gbe oyun lasiko to ba wa nile-ẹkọ, paapaa ile-ẹkọ girama. Bi mo ṣe n wo yin lonii, adura mi ni pe ẹ ko nii ṣi ẹsẹ gbe.

“Gẹgẹ bi Olori ti mo jẹ niluu Ilawọ, nko le laju silẹ ki aye awọn ọmọdebinrin bajẹ nipa gbigbe oyun airotẹlẹ, mo ṣetan lati ṣe iranlọwọ to ba yẹ bi eyi lati daabo bo ohun to le dena eto ẹkọ ọmọdebinrin. Ohun to jẹ mi logun julọ ni pe ki n ri gbogbo yin lati wa ni ibi giga lọjọ iwaju, ki n si le fi yin yangan.”

Nigba toun naa n sọrọ, Kọmiṣanna feto awọn obinrin nipinlẹ naa, Ọnarebu Adijat Adelẹyẹ jẹ ko di mimọ pe ọrọ awọn ọmọdebinrin jẹ ileeṣẹ naa logun pupọ, idi ree to ni awọn fi ṣagbekalẹ oniruuru eto lati maa fi ṣegbe lẹyin awọn ọmọdebinrin nipinlẹ naa.

Ọnarebu Adelẹyẹ, ẹni ti alakoso eto, Arabinrin Jumọkẹ Adewusi ṣoju fun, fidi rẹ mulẹ pe ọpọ iṣẹlẹ ifiyajẹ awọn ọmọde lawọn ri nileeṣẹ wọn, to maa n jẹ ẹdun ọkan fun wọn.

“Gbogbo iwa ipa patapata ti awọn eeyan ba n hu si awọn eeyan, eyi ti ko tẹ iru eeyan bẹẹ lọrun lo tapa si ofin nileeṣẹ wa. Awọn iwa ki ẹgbọn maa ba aburo laṣepọ, ki baba maa ba ọmọ re laṣepọ, tabi ki ọkunrin maa fipa ba obinrin laṣepọ, paapaa awọn ọmọde lo ni ijiya labẹ ofin nileeṣẹ wa.

“Ẹnikẹni ti ko ba tii pe ọdun mejidinlogun, ọmọde ṣi ni. Ọkunrin to ba ba ọmọbinrin ti ko tii pe ọdun mejidinlogun laṣepọ, iwa ipa la maa ka a si, iru ẹni bẹẹ yoo si foju ba ile-ẹjọ bi ọwọ palaba rẹ ba segi. Ijọba ipinlẹ Ogun, paapaa ileeṣẹ wa koro oju si iwa buruku yii.

“Ko si ifẹ kankan to wa laaarin awọn ọmọ kekeeke lasiko yii, nitori pe irọ lo wa nibẹ. Ki gbogbo awọn ọmọde to ba n ni ọrẹkunrin lasiko yii, ki wọn tete lọ jawọ, nitori pe iwa ipa la ka a si. Asiko ree lati gbajumọ eto ẹkọ yin,” Kọmiṣanna sọ bẹẹ.

O wa gbe oṣuba kare fun ajọ VWETA CHADWICK ti wọn tun n pe ni Project Asha lori agbekalẹ naa, to si ni inu awọn maa n dun nigba ti awọn ba ri ajọ tabi ileeṣẹ to n ṣagbatẹru eto bayii lati din iṣẹ  ku.

“Inu wa maa n dun, iwuri lo si maa n jẹ fun wa, nigba ti a ba ri awọn alatilẹyin to le din ẹru wa ku, nitori pe ijọba ko le da gbogbo rẹ ṣe tan.”

Bakan naa, Arabinrin Joan Ejinavy to jẹ alakoso eto amuṣẹṣe fun ajọ ironilagbara ti VWETA CHADWICK, nigba to n ba awọn ọmọ naa sọrọ lori nnkan oṣu, o sọ pe kii ṣe arun, bi ko ṣe pe lara igbesẹ lati jẹ ojulowo ọmọbinrin ni.

Obinrin naa sọ pe kaakiri agbaye lawọn ti n ṣe eto yii lati fi ṣe idanilẹkọọ fawọn ọmọde, paapaa awọn ọmọdebinrin, to si ni ipa pupa lawọn ti ko nigbesi aye awọn ọmọdebinrin pẹlu ọpọlọpọ ẹri.

O ni oyun airotẹlẹ pọ nita lasiko yii, to si jẹ pe ọpọ awọn ọmọde ti wọn ṣi wa nile-ẹkọ lo n gbe oyun lasiko ti wọn ba wa nile-ẹkọ, eyi to lo ku diẹ kaato.

Ejinavy ṣalaye pe lati le mu adinku ba bi awọn ọmọdebinrin ṣe n gbe oyun, ti wọn si n di ẹni to n ta ata, epo kaakiri ori titi, lasiko to yẹ ki wọn wa nile-ẹkọ, lo jẹ ki awọn ṣagbekalẹ ọhun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI