Gbajugbaja oṣere nni, Okemẹsi jade laye - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, February 24, 2026

Gbajugbaja oṣere nni, Okemẹsi jade laye



Lonii, ọjọ kẹrinlelogun, oṣ Keji, ọdun 2024 ni iroyin ibanujẹ tun sọ lagboole tiata, nigba ti iroyin jade sita pe gbajugbaja oṣere nni, Bamidele Tope Saint, tọpọ awọn eeyan mọ si Okemẹsi ti jade laye.

Nnkan bi agogo mejila ku iṣẹju mẹwaa aarọ oni, la gbọ pe dokita kede rẹ pe o ti ku.

O pẹ diẹ ti wọn sọ pe ọkunrin naa wa lori idubulẹ aisan, to si ti na ọpọlọpọ owo lati fi tọju ara rẹ.


Igba to di pe ko si agbara mọ, lo di ẹni to n gbe ninu ile kan, to si n da gbe nibẹ, titi digba ti ọlọjọ fi de.

A gbọ pe oogun ti wọn sọ pe oṣere naa lo, lo yiwọ, to si wa ni baaku-baala fun wakati diẹ ko to di pe ẹlẹmi gba a.

Ọkan lara awọn oṣere akẹgbẹ rẹ, to jẹ ki gbogbo aye mọ pe ọkunrin naa wa lori idubulẹ aisan tipẹ, Tony Montana Jeff lo kede iku Okemẹsi lori ikanni ayelujara ti Instagram nirọlẹ oni.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI