Opin de ba aye familete-ki-n-tutọ ti awọn bandiiti n jẹ ni Kwara - Ọgagun Olufemi Olatubosun sọrọ idaniloju - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, February 24, 2026

Opin de ba aye familete-ki-n-tutọ ti awọn bandiiti n jẹ ni Kwara - Ọgagun Olufemi Olatubosun sọrọ idaniloju

 
Olori awọn oṣiṣẹ nileeṣẹ ologun ilẹ Naijiria, Ọgagun Olufemi Olatubosun ti fidi rẹ mulẹ pe opin ti de ba gbogbo aye alakata ti awọn agbebọn aṣekupani, iyẹn bandiiti n jẹ nipinlẹ Kwara, pẹlu ifilọlẹ ikọ ajagun ti wọn pe ni 'Operation Savannah Shield'.

“Ọlọlajulọ, gomina, idi pataki ti mo fi wa ṣe abẹwo sii yin ni lati ṣe ifilọlẹ ikọ ajagun Operation Savannah Shield lati gbogun ti awọn bandiiti agbebọn," Ọgagun Olatubosun sọ bẹẹ fawọn akọroyin leyin ipade pẹlu Gomina AbdulRahman AbdulRazaq.

Ọgagun Olatubosun jẹ ko di mimọ pe ohun to ṣe pataki foun ni lati ba gomina ati awọn ọmọ ipinlẹ naa kẹdun awọn to padanu ẹmi wọn ninu ikọlu to waye laipẹ.

"A maa gbiyanju lati wa ọna lati gbogun ti awọn bandiiti naa, ka si le wọn danu kiro nj ni Kwara," o sọ bẹẹ.

Ṣugbọn nigba toun naa n sọrọ, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq sọ pe awọn adojukọ wọn lẹka eto aabo, lo jẹ ki wọn pe fun iranlọwọ ileeṣẹ ologun lati daabo bo awọn araalu.

Gomina sọ pe "Awọn ipenija wa, gẹgẹ bi alaga ẹgbẹ gomina nilẹ Naijiria, a wa ba a yin nigba miran lati ran wa lọwọ. A ni ipenija, o si ṣe pataki fun wa lati wa ọna abayọ, idi ree ti a fi ṣagbekalẹ apapọ ileeṣẹ eleto aabo ti a pe ni 'Operation Savannah Shield'.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI