Fun awọn eeyan lati lo anfaani eto aawẹ Ramadaani to wa nita lasiko yii lati di onile lori, ileeṣẹ Adron Homes and Properties Limited ti ṣagbekalẹ eto ara-ọtọ fun awọn onibara wọn, to fi mọ awọn onibara tuntun.
Anfaani eto ẹdinwo lori awọn dukia kaakiri ilẹ Naijiria ni ileeṣẹ Adron Homes ti gbe kalẹ fun gbogbo awọn to ba dowopọ pẹlu wọn.
Ileeṣẹ Adron Homes ni awọn fẹ ki awọn ayalegbe lo anfaani eto aawẹ Ramadaani to wa nita lasiko yii, lati di onile lori.
Anfaani ọhun ni ko wọpọ rara lagboole awọn oniṣowo dukia kaakiri Naijiria
Ninu atẹjade ti awọn alakoso ileeṣẹ naa fi sita, wọn jẹ ko di mimọ pe eto naa to bẹrẹ l'ogunjọ, oṣu Kinni, ni yoo pari lọjọ kẹfa, oṣu Kẹrin, ọdun 2026.
Wọn ni agbekalẹ naa ni lati ṣe iranlọwọ fun awọn ọmọ Naijiria lati le jẹ ki wọn san owo dukia ti wọn ba fẹ diẹ-diẹ, leyi ti ko nii ga wọn lara.
Wọn ṣalaye pe awọn onibara yoo jẹ anfaani ida ọgbọn lori dukia ti wọn ba fẹ, ti wọn yoo si lo oṣu mẹrindinlogoji lati fi san owo wọn.
Siwaju sii ni wọn fidi rẹ mulẹ pe onibara to ba san ẹgbẹrun lọna igba naira, yoo gba ẹbun nla lasiko iṣinu, nigba ti awọn to ba san ẹgbẹrun lọna irinwo naira yoo gba ẹni ikirun igbalode.
Yatọ si eyi, oniruuru anfaani lo tun wa nilẹ kaakiri agbegbe ti dukia wọn wa lawọn agbegbe bii Ekoo, Shimawa, Sagamu, Atan–Ota, Papalanto, Abeokuta, Ibadan, Osun, Ekiti, Abuja, Nasarawa, ati Niger states.
No comments:
Post a Comment