Ijọba Kwara kede gbale-gbata lọjọ Satide - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, February 27, 2026

Ijọba Kwara kede gbale-gbata lọjọ Satide


Ijọba ipinlẹ Kwara ti kede pe eto igbale-gba-'ta yoo waye kaakiri ipinlẹ naa, lati le jẹ ki ipinlẹ ọhun wa ni imọtoto.

Ọjọ Abamẹta, opin ọsẹ yii ni eto naa yoo waye, nibi ti gbogbo  araalu yoo ti kopa, laaarin agogo meje si mẹwaa owurọ.

Ninu atẹjade ti ileeṣẹ to n ri sọrọ eto ayika nipinlẹ naa fi sita lonii, ọjọ Ẹti, wọn jẹ ko di mimọ pe ko nii si igbokegbodo ọkọ laaarin asiko naa.

Atẹjade ọhun ti Kọmiṣanna, Hajia Nafisat Musa Buge buwọ lu fudu rẹ mulẹ pe ẹnikẹni tọwọ ba tẹ lai kopa ninu eto naa yoo foju winna ofin.

O ni isede yoo wa fun araalu, paapaa awọn awakọ, ati pe ẹnikẹni to ba tapa si aṣẹ ijọba yoo foju ba ile-ẹjọ alagbeka to ba wa nitosi, ti wọn yoo si gba idajọ to ba tọ si wọn.

O wa rọ awọn araalu lati ṣamulo eto naa daadaa lati tun ile ati ayika wọn ṣe, lati le jinna si ajakalẹ arun, nitori ilera lọrọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI