Idunnu lo ṣubu lu ayọ Ọgbẹni Solanke Francis Taiwo nigba ti ijọba ipinlẹ Ogun fi ile nla ta a lọrẹ, gẹgẹ bi olukọ to ṣe daadaa julọ nipinlẹ Ogun.
Yatọ si ẹbun tijọba ipinlẹ Ogun gbe le e lọwọ, ijọba apapọ Naijiria naa tun fi ẹbun ọkọ bọginni ta a lọrẹ, lori bo ṣe tayọ.
Ile-ẹkọ Ansa-Ur-Deen Main School I to wa ni Kemta Lawa niluu Abẹokuta la gbọ pe Ọgbẹni Solanke ti n ṣiṣẹ olukọ, ti wọn si lo n gbajumọ iṣẹ rẹ.
Ṣaaju akoko yii ni Ọgbẹni Solanke ti gba aadọta miliọnu lọwọ ijọba apapọ nibi ipade apapọ awọn olukọ to waye niluu Abuja laipẹ yii, nibi ti wọn ti gbe oṣuba kare fun un lori ifarajin rẹ si eto ẹkọ.
Nigba to n fa kọkọrọ ọkọ le olukọ naa lọwọ ni Oke-Mosan niluu Abẹokuta, Gomina Abiodun sọ pe lara awọn to gbe ogo ipinlẹ naa yọ ni Ọgbẹni Solanke.
Lara awọn to wa nibẹ ni Kọmiṣanna feto ẹkọ, Ọjọgbọn Abayomi Arigbabu; akọwe ileeṣẹ eto ẹkọ, Ọgbẹni Oloko; Olori ile igbimọ aṣofin, Ọnarebu Oludaisi Elemide ati awọn miran.
Gomina Dapo Abiodun sọ pe Ọgbẹni Solanke yoo gba ile adagbe olojule meji si agbegbe to ba wu, labẹ eto ile gbigbe nipinlẹ Ogun, iyẹn State Housing Scheme.



No comments:
Post a Comment