Idi pataki mẹrinla ti o fi gbọdọ ra dukia ni ileeṣẹ Adron Homes - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, February 12, 2026

Idi pataki mẹrinla ti o fi gbọdọ ra dukia ni ileeṣẹ Adron Homes


Ko si ohun ini to dara ti ẹda le ni laye, to kọja ile gbigbe ti yoo fi eeyan lọkan balẹ titi di ọjọ alẹ. Ọpọ lo si ti ko sọwọ awọn gbajuẹ ti wọn ti gba owo lọwọ wọn, lai ri ilẹ tabi ile wọn gba.

Lojuna lati ṣeto ayẹyẹ ọdun mẹrinla ti wọn ti n mu ayipada ba eto ile igbalode gbigbe nilẹ Naijiria, ileeṣẹ Adron Homes ti ṣagbekalẹ idi pataki mẹrinla ti araalu gbọdọ fi ba wọn dowopọ lati di onile lori.

Ọpọ awọn eeyan lo ti jẹri nipa rira ojulowo dukia nileeṣẹ Adron Homes lai daamu rara.

Ninu atẹjade ti awọn alakoso ileeṣẹ naa fi sita l'Ọjọbọ, ọsẹ yii, wọn ni ogun nla ni dukia jẹ nigbesi aye ẹda, to si jẹ aabo ọlọjọ pipẹ, ọrọ ninu ati idagbasoke agbegbe.

Awọn alakoso naa sọ pe lati ọdun mẹrinla sẹyin, ni awọn ti n pese dukia olowo pọọku fun awọn araalu, to si jẹ pe ko si ẹni ti ko le ra ilẹ si ọdọ wọn.

Wọn ni ẹnu ọna abawọle awọn agbegbe dukia wọn lo ni eto aabo to pe ye ninu, pẹlu ayika to wuyi fun igbadun ati irọrun ọjọ alẹ.

Bakan naa ni wọn tun ṣalaye nipa awọn iwe ẹri to fontẹ lu ojulowo dukia lọdọ wọn.

Yatọ si eyi, akọsilẹ rere ni wọn tun ni lati maa ran ogunlọgọ awọn onibara lọwọ lati kọ ilẹ to wu wọn lọkan, paapaa awọn eyi ti wọn  foju sọna fun.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI