Sunday Igboho sọ ọna abayọ ti Nnamdi Kanu fi le bọ lọgba ẹwọn - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, February 13, 2026

Sunday Igboho sọ ọna abayọ ti Nnamdi Kanu fi le bọ lọgba ẹwọn


Olori ajijangbara fun idasilẹ ilẹ Oodua, Oloye Sunday Adeniyi Adeyemo tọpọ awọn eeyan tun mọ si Sunday Igboho ti gba olori ajijangbara ilẹ Biafra lamọran lati lo ọgba atinuda lati ba ijọba Naijiria sọrọ, iyẹn to ba ṣetan lati gba itusilẹ kuro lọgba ẹwọn.

Igboho lo sọrọ naa ninu atẹjade to fi sita lọjọ Ẹti, ọjọ kẹtala, oṣu Keji, ọdun 2026 lati ọwọ agbẹjọro rẹ, PelumiOlajengbesi.

Ninu atẹjade naa lo ti gbe oriyin fun Kanu lori bo ṣe f'opin si aṣẹ jokoo sile to gbe kalẹ tipẹ, eyi to n ṣakoba fun eto ọrọ aje ati igbayegbadun araalu lẹkun Guusu ilẹ Naijiria lati bi ọdun meloo sẹyin.

O ṣapejuwe ifopin si iwọde ọlọsẹ-ọsẹ naa gẹgẹ bi erongba rere to ṣe pataki lasiko yii, to si ni igbesẹ naa jẹ ki eto ọrọ aje ẹkun naa pada bọ sipo pẹlu irọrun.

Igboho tun sọ pe igbesẹ naa ti n fi apẹẹrẹ han pe ọkunrin naa ti n fẹ ajọsọ rere laaarin oun pẹlu ijọba Naijiria, dipo ikọlu to n ṣe ni gbogbo igba.

“Oloye Sunday Adeyemo fẹẹ gbe oṣuba kare fun olori ajijangbara ilẹ Biafra, Mazi Nnamdi Kanu, lori bo ṣe fopin si jijoko sile ni gbogbo ọjọ Aje kaakiri ẹkun Guusu Ila-Oorun ilẹ Naijiria,” atẹjade naa sọ bẹẹ, to si ni igbesẹ naa fopin si didabaru eto ọrọ aje ọlọdun marun-un.

“Oloye Sunday Igboho rọ gbogbo awọn to n ko ereninu eto jijoko sile naa kaakiri ẹkun Guusu Ila-Oorun lati dẹkun gbogbo iwa ipa naa, lati le gba alaafia laaye, ki eto ọrọ aje ẹkun naa si le ni idagbasoke sii.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI