Ifẹ to wa laarin wa ni ko jẹ ki ọrọ baba isalẹ da wahala silẹ laaarin emi ati Gomina Abiọdun l'Ogun - Ọṣọba - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, February 13, 2026

Ifẹ to wa laarin wa ni ko jẹ ki ọrọ baba isalẹ da wahala silẹ laaarin emi ati Gomina Abiọdun l'Ogun - Ọṣọba


Gomina tẹlẹri nipinlẹ Ogun, Oloye Olusegun Osoba ti sọ pe ajọṣepọ to dan mọnran to wa laaarin oun pẹlu gomina ipinlẹ naa, Ọmọọba Dapo Abiodun lo fa a, ti ko fi si aawọ lori ọrọ baba isalẹ latigba to ti n ṣe ijọba.

Oloye Olusegun Osoba sọ pe niwọn igba ti ibaṣepọ to dan mọnran ti wa laaarin oun pẹlu Abiọdun, ko tun si ohun kan to le dija silẹ laaarin wọn, paapaa lori ohun to nii ṣe pẹlu baba isalẹ.

Arẹmọ Osoba lo sọrọ yii lasiko to n dahun ibeere lati ọdọ awọn akọroyin niluu Abẹokuta l'Ọjọbọ, ọjọ kẹtala, oṣu Keji, ọdun 2026.

Nigba to n sọrọ, Osoba ṣalaye pe latigba ti Gomina Abiodun ti de ori ipo naa lọdun 2019, loun ko ti da si ọrọ iṣẹjọba rẹ, to si loun fi silẹ lati ṣejọba naa bo ba ṣe wu u.

O sọ pe oun ko tun figba kan fi orukọ ẹnikẹni ranṣẹ si Gomina Abiodun lati fi si ipo ijọba latigba naa, titi di asiko yii.

Akirọgun ilẹ Ẹgba naa tun fidi rẹ mulẹ pe gẹgẹ boun ṣe jẹ gomina tẹlẹ ati agba alẹnulọrọ ninu ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress nilẹ Naijiria, niṣe ni gomina naa bọwọ foun, toun naa si duro lori ipo oun.

"Mo bọwọ fun un gẹgẹ bi alakoso ati baba ipinlẹ yii. Mo fun un ni ọwọ rẹ, bẹẹ loun naa si bọwọ fun mi pada," Osoba sọ bẹẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI