Gomina Dapo Abiodun tipinlẹ Ogun ti ṣi opopona Lantoro si Oke-Yidi to wa nijọba ibilẹ Guusu Abẹokuta, pẹlu idaniloju pe iṣakoso oun yoo tubọ ṣe ọpọ opopona kaakiri ipinlẹ naa.
Ọjọbọ, ọsẹ yii ni gomina ati awọn alẹnulọrọ ninu ijọba, ilu, to fi mọ awọn Ọba alaye, ati bẹẹ bẹẹ lọ ṣiṣọ loju opopona naa, fun lilo araalu.
Lati ọpọlọpọ ọdun sẹyin ni awọn awakọ ti kọ opopona naa silẹ, nitori bi ko ṣe dun-un gba fun wọn.
Ọpọ igba ni awọn awakọ, paapaa awọn olugbe agbegbe naa to gbajúmò daadaa niluu Abẹokuta ti ke.gbajare si ijọba lati boju aanu wo opopona naa fun atunṣe.
Nigba to n sọrọ, Gomina Abiodun jẹ ko di mimọ pe lara awọn ileri toun ṣe lasiko ipolongo idibo ni lati ṣiṣẹ lawọn opopona to ti n dẹnukọlẹ, fun irọrun igbokegbodo ọkọ ati araalu.
O wa rọ awọn araalu lati ṣamulo opopona naa daadaa, ko le baa jẹ alalopẹ.
No comments:
Post a Comment