Ipade Gbogboogbo: APC gbe iṣẹ nla le Gomina AbdulRazaq lọwọ fun aṣeyọri - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, February 26, 2026

Ipade Gbogboogbo: APC gbe iṣẹ nla le Gomina AbdulRazaq lọwọ fun aṣeyọri


Ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC lapapọ ti yan Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara gẹgẹ bi igbakeji igbimọ ti yoo ṣakoso eto ipade gbogboogbo ẹgbẹ naa to n bọ laipẹ.

Ọjọ kẹtadinlọgbọn ati ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2026 ti a wa yii ni ipade gbogboogbo naa yoo waye nilui FCT, Abuja.

Nipa ipade awọn alakoso ati alẹnulọrọ to waye l'Ọjọru, ọsẹ yii, APC sọ gomina yoo ṣe igbakeji alaga igbimọ ẹlẹni mẹtalelaadọrin ti wọn pe ni Central Coordination Committee (CCC).

Yatọ si eyi, wọn tun kede Gomina AbdulRazaq gẹgẹ bi alaga igbimọ eto gbogboogbo naa ti wọn pe ni Convention Legacy and Rapporteur Committee.

Nigba to n kede awọn ọmọ igbimọ naa, alaga apapọ f'ẹgbẹ APC nilẹ Naijiria, Ọmọwe Nentawe G. Yilwatda, ṣapejuwe eto ọhun gẹgẹ bi asiko lati dari ẹgbẹ naa soju ọna itẹsiwaju.

Yilwatda gba gbogbo wọn lamọran lati ṣe ṣoju saaju, ki wọn jẹ ki gbogbo ohun ti wọn ba n ṣe han si gbogbo ọmọ ẹgbẹ naa.

Lara awọn gomina to tun wa ninu igbimọ naa ni: Umo Bassey Eno, Douye Diri, Hyacinth Alia, Babagana Umara Zulum, Bassey Otu, Sheriff Oborevwori, Francis Nwifuru, Monday Okpebholo, Abiodun Oyebanji, ati Peter Mbah.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI