Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni iṣẹlẹ naa ṣi n jẹ kayeefi leti ọpọ awọn ara agbegbe Ijoko to wa nipinlẹ Ogun, pẹlu bi wọn ṣe sọ pe agbero kan lu ọlọkada pa nitori tikẹẹti ọgọrun kan naira to fẹẹ ja.
Ale ọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii la gbọ pe iṣẹlẹ aburu naa waye, to si ba ọpọ awọn to wa nibẹ lọkan jẹ.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, wọn ni ori ọkada ni ọlọkada ọhun to n kọja lọ wa, ti agbero naa fi da a duro pe dandan ni ko ja tikẹẹti oun, to jẹ ọgọrun kan naira.
Wọn sọ pe niṣe ni ọlọkada naa fariga pe oun ko le ja tikẹẹti kankan ni asiko ti ilẹ ti ṣu, ati pe oun yoo ja a ni ọjọ keji.
Eyi ni wọn lo jẹ ki ọrọ naa di ariwo, to fi di pe awọn agbero yooku lọ sibẹ lati fẹẹ fi tipa gba owo lọwọ ọmọkunrin ọhun.
Nibi ti wọn ti n fa ọrọ naa la gbọ pe ọkan lara wọn ti gba ọlọkada yii lẹṣẹ, tiyẹn si gbabẹ sọda sọrun alakeji loju ẹsẹ.
A gbọ pe bi kete ti wọn rii pe ọlọkada naa fidi lelẹ, ti wọn si rii pe ẹlẹmin ti fẹẹ gba a, ni gbogbo wọn ti na papa bora, ki ọwọ agbofinro ma ba a tẹ wọn.
Wọn sọ pe loju ẹsẹ ni gbogbo agbegbe naa ti pa lọlọ, ti ko si si agbero kankan nita mọ, pẹlu bi gbogbo wọn ṣe juba ehoro.
Latigba naa ni wọn lawọn ọlọpaa ti bẹrẹ iwọde, ti wọn ni afi k’awọn gbẹsan iku ọkan lara wọn, nitori pe iya naa ko le jẹ wọn gbe.
Kaakiri awọn agbegbe bii Lambẹ, Agbado ati Akute ni awọn ọlọkada ti fẹhonu han si awọn alakoso, ti wọn si n bẹ ijọba pe idajọ ododo gbọdọ waye.
Ọkan lara awọn awakọ lagbegbe naa, Raṣheed to ba awọn akọroyin sọrọ jẹ ko di mimọ pe ọlọkada meji ni awọn agbero naa fi igo gun, ṣugbọn to jẹ pe ọkan lara wọn lo pada ku.
“Nitori tikẹẹti ọgọrun kan naira ni wọn ṣe n ja. Bi ere ni ọrọ naa ṣe ṣẹlẹ lalẹ ọjọ Iṣẹgun, ko to di pe ọrọ yiwọ. Ipinlẹ Nasarawa ni ọlọkada to padanu ẹmi rẹ naa ti wa. Awọn akẹgbẹ rẹ ti wa n koju awọn agbero lagbegbe Lambẹ, Ijoko ati apa kan ni Akute bayii lati fẹhonu han,” Raṣheed sọ bẹẹ.
Ọlọkada kan naa to tun sọrọ jẹ ko di mimọ pe nnkan ko lọ deede mọ latigba naa, pẹlu bo ṣe sọ pe inu awọn ko dun si ohun to ṣẹlẹ.
Ganiyu lo fidi rẹ mulẹ pe ọbẹ ni agbero naa fi gun ọlọkada naa p a, kii ṣe igo.
“Latigba naa ni awa ọlọkada kan ko ti ṣiṣẹ, to si jẹ pe awọn diẹ ni wọn n ṣiṣẹ. Awọn ọlọpaa si ti bẹrẹ iṣẹ iwadii, ti wọn si ti rọwọ to awọn afurasi kan,” Ganiyu ṣalaye bẹẹ.
Gbogbo akitiyan lati ba agbẹnusọ ọlọpaa, Oluṣeyi babaṣeyi sọrọ lati fidi iṣẹlẹ naa mulẹ lo ja si pabo titi digba ti a pari akojọpọ iroyin yii.
No comments:
Post a Comment