Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti sọ pe ọwọ awọn ti tẹ gendekunrin kan, Gafaru Rasaki pẹlu ori oku ti ko din ni mẹrini, eyi to ṣẹṣẹ lọ ge.
Agbegbe Ṣagamu lọwọ palaba Rasaki ti segi, gẹgẹ bi agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ naa, Oluṣeyi Babaṣeyi ṣe sọ ninu atẹjade to fi sita l’Ọjọbọ, ọsẹ yii.
Babaṣeyi sọ pe ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kinni, ọdun 2026 yii lọwọ tẹ Rasaki lasiko to n pada bọ lati ibi to ti lọ wu ori oku naa.
O ni awọn ọlọpaa ẹkun Shakura to wa niluu Ṣagamu lo rọwọ to ọkunrin naa ti ko niṣẹ meji ju tita ẹya ara oku tabi eeyan naa lọ.
Agbẹnusọ naa fidi rẹ mulẹ pe Rasaki jẹwọ fawọn ọlọpaa lasiko ti wọn n ṣe ifọwerọ pẹlu ẹ wi pe itẹku kan to wa nitosi loun ti lọ wu ọkan kan, toun si ge ori rẹ.
“Lọjọ kọkanlelogun, oṣu Kinni, ọdun 2026, awọn ọlọpaa ẹkun Shakura fọwọ ṣikun ofin mu ọkunrin kan to n jẹ Gafaru Rasaki ti wọn ka ori eeyan mẹrin mọ lọwọ,” atẹjade naa ṣalaye bẹẹ.
“Nibi ifọrọwerọ ati iwadii, aṣiri tu sita pe niṣe ni afurasi naa lọ wu awọn oku to wa ni itẹku, to si bẹrẹ sii ge ori wọn, eyi lo si lodi si ofin ilẹ wa.”
O ni kete ti awọn ba pari iwadii awọn lẹkunrẹrẹ lati mọ gbogbo awọn ti ọrọ naa kan, ko to di pe Rasaki foju ba ile-ẹjọ.
No comments:
Post a Comment