Amugbalẹgbẹ pataki fun gomina ipinlẹ Kwara lori eto iroyin igbalode, Akewejẹ Olayinka Fafoluyi ti ba gbogbo mọlẹbi Oloogbe Ọnarebu Olatunde Tunji kẹdun iku rẹ.
Ọnarebu Olatunde Tunji to jẹ igbakeji alaga ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC ni wọọdu Ajade kinni to wa nipinlẹ Kwara lo dagbere faye lojiji, iyẹn laipẹ yii.
Iku naa ba ọpọ eeyan lojiji, to si mu ki awọn to mọ ọkunrin naa maa kọminu.
Nigba to n ṣapejuwe Tunji, Akewejẹ Fafoluyi jẹ ko di mimọ pe lara awọn ọmọ ẹgbẹ to fi tọkantọkan sin ẹgbẹ naa ni Oloogbe naa jẹ.
Fafoluyi sọ pe ipa ti oloogbe naa ko ninu eyo idagbasoke ati ilọsiwaju ẹgbẹ APC ni agbegbe Ajase ko ṣee fọwọ rọ sẹyin.
O ni awọn yoo ṣafẹri ọkunrin naa gidigidi, nitori pe ẹni to ṣee gbe ara le nidi oṣelu ni.
Bakan naa lo jẹ ko di mimọ pe ojiji ni iku Tunji ba wọn, to si jẹ ẹdun ọkan fun wọn, nitori pe asiko ti awọn nilo rẹ lo fi aye silẹ.
O wa gbadura pe ki Ọlọrun tẹ ọkunrin naa si afẹfẹ rere, ko si tu gbogbo awọn mọlẹbi to fi silẹ ninu.
No comments:
Post a Comment