Gomina AbdulRazaq gbe oṣuba kare fun Aarẹ Tinubu lori abẹwo itan to ṣe lọ silẹ Gẹẹsi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Thursday, March 26, 2026

Gomina AbdulRazaq gbe oṣuba kare fun Aarẹ Tinubu lori abẹwo itan to ṣe lọ silẹ Gẹẹsi


Alaga igbimọ awọn gomina nilẹ Naijiria, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq ti gbe oṣuba kare fun Aarẹ Bola Ahmed Tinubu lori abẹwo itan tuntun to ṣe lọ silẹ Gẹẹsi laipẹ yii.

 Gomina AbdulRazaq, to tun jẹ gomina ipinlẹ Kwara nibi abẹwo to ṣe lọ sile Aarẹ Tinubu tp wa l'Ekoo, lati kii fun ayẹyẹ itunu aawẹ to ṣẹṣẹ pari, iyẹn Eid-el-Fitr lo ti gbe oṣuba kare fun aarẹ naa.

Nibi abẹwo ti aarẹ ṣe naa lo ti tọwọ bọwe adehun nipa ajọsọ tuntun lori okoowo ṣiṣẹ pẹlu ijọba ilẹ Gẹẹsi fun anfaani awọn ọmọ Naijiria.

“Nigba ti erongba wa ti da lori ibaṣepọ to dan mọnran pẹlu ijọba ilẹ Gẹẹsi, abẹwo naa to waye fun igba akọkọ lẹyin ọdun mẹtadinlogoji, jẹ eyi to ni igboya, to si ni ipa rere. O jẹ ipele ọtun ninu ibaṣepọ pẹlu ijọba Naijiria, a si dupẹ fun eyi,” Gomina AbdulRazaq sọ bẹẹ.

“Ni apapọ, a ni lati rii pe ọrọ iṣoro to n doju kọ eto aabo gbọdọ dohun igbagbe. Nipa ti ọlọpaa ipinlẹ, igbesẹ ti n lọ lọwọ pẹlu awọn oniruuru ileeṣẹ eleto aabo leyi ti oludamọran pataki lori eto aabo ati ẹgbẹ awọn gomina nilẹ Naijiria ti n kopa wọn. NGF yoo gbe awọn iwe naa lọ sile igbimọ aṣofin lati ṣagbeyẹwo rẹ.’’

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI