Titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii ni iṣẹlẹ ijamba ina to f’ẹmi ọmọ iya kan naa meji ṣofo danu nipinlẹ Ondo ṣi n jẹ kayeefi f’awọn to gbọ, paapaa awọn ara agbegbe ti ijamba ọhun ti waye.
Ọjọ kejidinlogunm oṣu Kẹta, ọdun 2026 ti a wa yii la gbọ pe ijamba ina ọhun ṣẹlẹ lojule kinni, adugbo Ọlaribigbe, agbegbe Zion to wa niluu Ode-Aye to wa nijọba ibilẹ Okitipupa.
Ko s’ohun meji to n ba awọn eeyan to gbọ lọkan jẹ, bi ko ṣe pe ọmọ ti ọjọ ori wọn ko ju ọdun mẹrin si mẹfa lọ.
Queen Ohwo, ọmọ ọdun mẹfa ati Everlyne Ohwo toun jẹ ọmọ ọdun mẹrin lawọn mejeeji ti wọn gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra ninu ijamba ina ọhun.
Nigba to n fidi iṣẹlẹ aburu naa mulẹ, agbẹnusọ ọlọpaa ipinlẹ naa, Abayọmi Jimọh sọ pe awọn ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lati mọ kulẹkulẹ ohun to ṣẹlẹ.
Inu ibanujẹ ọkan ni baba ati iya awọn ọmọ naa, Ọgbẹni ati Arabinrin Ohwo Peter wa titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii.
Jimọh fidi rẹ mulẹ pe awọn ọmọ naa jona kọja idanimọ nigba ti wọn yoo fi ri wọn, to si lawọn ọlọpaa lo ko oku wọn lọ si mọṣuari ile iwosan alabọde tiluu Ode-Aye.
Agbẹnusọ naa jẹ ko di mimọ pe awọn obi awọn ọmọ naa ko tii gbadun ara wọn, ati pe niṣe ni iṣẹlẹ naa ṣi n dabi ala loju wọn.
O ni iwadii tawọn ṣi n ṣe, jẹ ko ye awọn pe ijamba naa ṣee ṣe nipa aikiyesara ina ounjẹ ti wọn n da ninu ile.
Ṣugbọn ṣa, ọga ọlọpaa pata nipinlẹ naa, Adebọwale Lawal ti paṣẹ pe ki iwadii ijinlẹ bẹrẹ lati mọ kulẹkulẹ ohun to ṣẹlẹ, ti ijamba naa fi waye.
Lawal paṣẹ pe ki ọga ọlọpaa ẹkun Ode-Aye lọ sibi iṣẹlẹ lati fọrọ wa awọn ara agbegbe ọhun lẹnu wo, nipa ajọṣepọ pẹlu ileeṣẹ panapana, lati mọ ipilẹ ijamba ina naa.
No comments:
Post a Comment