Ẹyin adiẹ gbowo lọri l’ọja agbẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, March 31, 2026

Ẹyin adiẹ gbowo lọri l’ọja agbẹ


Alaga ẹgbẹ awọn ọlọọsin adiẹ, PAN lorileede Naijiria, ẹka tipinlẹ Ekoo, Mọjeed Iyiọla ti ṣalaye nipa idi ti owo ẹyin adiẹ fi gbowo lori lawọn agbegbe kan lorileede Naijiria.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ẹgbẹrun mẹjọ ataabọ naira ni wọn n ta kireeti ẹyin adiẹ kan bayii lawọn agbegbe kan nilẹ Naijiria, leyi to di ohun to n kọ ọpọ awọn eeyan lominu.

Iyiọla nigba to n ba awọn akọroyin sọrọ laipẹ yii, o jẹ ko di mimọ pe bi wọn ko ṣe ri oromọ adiẹ ọsin ra, to si di ohun ti wọn n la kaka lati ri ra, lo fa a, ti owo ẹyin fi lọ soke.

O jẹ ko di mimọ pe gbogbo awọn ileeṣẹ ti wọn ti n sọ ẹyin di oromọ adiẹ fun sinsin lawọn eeyan ti lọ kowo fun wọn, lati gba a.

Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe “Ohun kan pataki to fa ọwọngogo ẹyin ni pe awọn agbẹ ọlọọsin adiẹ ti ta gbogbo adiẹ to n yin ẹyin tan, idi ree ti wọn ko fi ni anfaani si oromọ aadiẹ to n yin ẹyin.

“Nigba ti awọn ọlọọsin adiẹ ba lọ si ileeṣẹ ti wọn ti n sọ ẹyin di oromọ adiẹ, yatọ si pe ko si nilẹ, owo rẹ tun n lọ soke sii lọsẹ-ọsẹ,” Iyiọla sọ bẹẹ.

Ṣaaju asiko yii, ko to di pe ẹyin gbowo lori bayii, ẹgbẹrun marun-un ataabọ naira si ẹgbẹrun mẹfa naira ni wọn n ta kireeti ẹyin kan kaakiri Naijiria.

Ṣugbọn pẹlu bi owo ẹyin ṣe lọ soke yii, o tun ti wa gbowo lori ju kilo adiẹ kan ti wọn n ta laaarin ẹgbẹrun mẹfa si meje naira laaarin ọja.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI