Gbogbo awọn oṣiṣẹ patapata nileeṣẹ Adron Homes ni wọn ti fi idunnu han si ọga ati oludasilẹ wọn, Aarẹ Adetola EmmanuelKing fun ti ayẹyẹ ọjọ ibi ọdun mọkanlelaadọta.
Ọjọ keji, oṣu Kẹrin, ọdun 2026 ni Aarẹ EmmanuelKing pe ọdun mọkanlelaadọta loke eepẹ, ti gbogbo awọn eeyan ati afẹnifẹre kaakiri agbaye ai b ki alakoso agba naa ku oriire.
Ninu atẹjade ti awọn aṣoju ileeṣẹ naa fi sita, wọn ṣapejuwe ọga wọn gẹgẹ bi ẹlẹyinju aanu ti ipa rere rẹ ko le parẹ.
Wọn ni ilana ti Aarẹ EmmanuelKing fi lelẹ ni Adron Homes lo jẹ ki wọn maa tẹsiwaju, ki wọn si di gbajugbaja kaakiri agbaye.
Gbogbo wọn lo gbadura alaafia ati ẹmi gigun fun ọga agba naa.
No comments:
Post a Comment