L’Ọjọru, ọsẹ to kọja yii ni ọmọ aarẹ ilẹ Naijiria tẹlẹ, Oloye Oluṣẹgun Ọbasanjọ, iyẹn Iyabọ Ọbasanjọ lọ ṣabẹwo oṣelu sawọn ọba alaye kaakiri ilẹ Ijẹbu.
Iyabọ Ọbasanjọ lo lọ ṣepade pẹlu awọn ọba alaye naa lati jẹ ki wọn mọ erongba rẹ lati jade du ipo gomina ipinlẹ Ogun ninu eto idibo to n bọ lọdun 2027.
Abẹwo ọhun lo waye ninu aafin Awujalẹ ilẹ Ijẹbu, nibi ti gbogbo awọn ọba alaye ti ko din ni mẹrindinlọgọta to di ilẹ Ijẹbu mu ti ṣeleri lati ṣatilẹyin fun un lasiko eto idibo to n bọ.
Eyi ni lara awọn igbesẹ lati fa oju awọn eeyan mọra, ati lati jẹ ki awọn araalu mọ ipinnu rẹ fun ipo gomina to n foju sọna fun.
Igbimọ awọn ọba alaye ti Ọba Lawrence Jaiyeọba Adebajo jẹ alaga rẹ, ni wọn ti ṣa iwure ati adura atilẹyin fun ọmọ aarẹ tẹlẹ naa, ti wọn si fọkan rẹ balẹ pe awọn wa lẹyin rẹ digbi.
Nibẹ lo ti jẹ ko di mimọ pe ipinnu rere loun ni fun idagbasoke ati ilọsiwaju nipinlẹ naa, ati pe awọn iṣẹ toun ṣe silẹ lasiko toun fi wa nipo sẹnetọ, loun fẹ wa pari gẹgẹ bii gomina.
O ran wọn leti nipa awọn akitiyan rẹ gẹgẹ bi kọmiṣanna ati sẹnetọ to ṣoju ẹkun aarin gbungbun ipinlẹ Ogun.
Nigba ti wọn n sọrọ, awọn ọba naa jẹ ko di mimọ pe Iyabọ Ọbasanjọ ni yoo jẹ oludije akọkọ ti yoo kọkọ fi erongba rẹ, nipa pipe awọn ọba alaye to sunmọ araalu julọ lati fi to wọn leti.
Wọn jẹ ko di mimọ pe obinrin naa ni iwa irẹlẹ pẹlu ibọwọ fun ipo ori ade, leyi to jẹ ki wọn gbe oṣuba kare fun un.
Lara awọn ọba alaye to tun wa nibi ipade naa ni Ọba Anthony Alakija, Ọba Sikiru Okuribido, Ọba Abdulrasaq Adenugba, ati awọn miran ti a ko le darukọ tan nijọba ibilẹ mẹfa to wa nilẹ Ijẹbu.
Iroyin tẹ AWIKONKO lọwọ jẹ ko di mimọ pe fun bi wakati meji si mẹfa ni Iyabọ Ọbasanjọ fi ba awọn ọba alaye naa ṣe ipade ikọkọ, leyi ko sẹni to mọ ohun ti wọn sọ nibẹ.
Ṣugbọn bi wọn ṣe jade, lo fidi rẹ mulẹ pe gbogbo awọn ọba naa ni wọn ṣetan lati ṣatilẹyin fun obinrin naa to ti lo ọpọlọpọ ọdun loke okun, nibi to ti gboye ọjọgbọn, lẹyin to padanu ipo sẹnetọ lọdun 2011.

No comments:
Post a Comment