Oriire Nla! Ilu Ekan ni Kwara f'oye tuntun da Aekewejẹ Fafoluyi lọla - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, March 29, 2026

Oriire Nla! Ilu Ekan ni Kwara f'oye tuntun da Aekewejẹ Fafoluyi lọla


Ọrọ Yoruba to sọ pe bi ọmọ ẹni ba dara, o yẹ ka wi, lo lọ nibamu pẹlu bi awọn araalu Ekan to wa nipinlẹ Kwara ṣe fi oye nla tun da amugbalẹgbẹ gomina ipinlẹ Kwara lori eto iroyin igbalode, Oloye Olayinka Fafoluyi lọla.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, 'Fiwajoye' ni orukọ ipo tuntun ti wọn fi ta Fafoluyi, ẹni to jẹ Akewejẹ tiluu Aran-Orin lọla.

Iroyin to tẹ wa lọwọ sọ pe Ọba David Adekunle Olaniyan, Orifẹmiloye, Ọdunun Asọludẹrọ akọkọ, Elekan tiluu Ekan ati awọn alakoso ilu naa buwọ lu ipo naa nibi ipade awọn alakoso ilu naa ti wọn ṣe lọjọ kẹfa, oṣu Keji, ọdun 2026 ti a wa yii.

Ninu lẹta ti wọn fi ranṣẹ si Fafoluyi, wọn jẹ ko di mimọ pe gbogbo ilu lo fara mọ oye tuntun naa, ti Kabiyesi wọn si buwọ lu u.

“A n kọ iwe yii lati fi to yin leti pe Alayeluwa, Ọba David Adekunle Olaniyan, Orifemiloye, Odundun Asodedero I, Elekan of Ekan, ati igbimọ iṣakoso ilu Elekan, nibi ipade wọn to waye lọjọ kẹfa, oṣu Keji, ọdun 2026, fẹnuko lati fi oye Fiwajoye tiluu Ekan da yin lọla,” lẹta naa sọ bẹẹ.


A gbọ pe awọn ipa ribiribi ti Akewejẹ ti ṣe lagbegbe naa, lo jẹ ki wọn pinnu lati fi oye naa da a lọla, lati le fun un ni koriya lati ṣiṣẹ siwaju sii.

Gbagede ọgba ile-ẹkọ alakọbẹrẹ ti United Anglican to wa niluu Ekan ni eto ifinijoye naa yoo ti waye lọjọ Kẹrin, oṣu Kẹrin, ọdun 2026.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI