Lọsẹ to kọja lawọn agbebọn yawọ ile ijọsin ECWA to wa lagbegbe Omugo, ti wọn si ji mẹjọ gbe nibẹ.
Awọn oṣiṣẹ eleto aabo bii ọmọ ogun, ọlọpaa, Sifu Difẹnsi ati awọn ọlọdẹ ti a tun mọ si Fijilante la gbọ pe wọn dide lati ṣe iranwọ f'awọn ti wọn jigbe naa.
Ijọba ti wa gbe oriyin fun gbogbo awọn oṣiṣẹ eleto aabo to lọwọ ninu gbigba awọn ti wọn jigbe naa silẹ kuro lahaamọ awọn ajinigbe.
Siwaju sii ni ijọba bu ẹnu atẹ lu bi awọn agbebọn ṣe n ṣe ikọlu si awọn ile ijọsin kaakiri ipinlẹ naa, to si lohun ko nii kawọ gbera lori rẹ.
Ninu atẹjade ti ijọba fi sita lọjọ Aiku to kọja yii, ijọba rọ gbogbo awọn eleto aabo, to fi mọ awọn aṣọgbo ati awọn ọlọdẹ, to fi mọ awọn araalu lati ṣiṣẹ papọ lati gbogun ti iwa ijinigbe.
No comments:
Post a Comment