Ile-ẹjọ giga apapọ to fikalẹ siluu Asaba nipinlẹ Delta ti sọ pe ki Baale ile kan, Agbanashi Young lọ fi ẹwọn oṣu mẹfa gbako gbara pẹlu iṣẹ aṣekara lori ẹsun ṣiṣe owo naira niṣekuṣe.
Onidajọ F. A. Olubanjo lo gbe idajọ naa kalẹ l'Ọjọru, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹta, ọdun 2026.
Ẹsun kan pere ni wọn fi kan Young niwaju ile-ẹjọ, eyi ti wọn lo tako abala kọkanlelogun, ipinlẹ kẹta ninu iwe ofin banki apapọ Naijiria, CBN, ti ọdun 2007.
Ẹsun naa ka pe "Iwọ Agbanashi Young (ọkunrin) ni nnkan bi ọjọ kẹwaa, oṣu Kọkanla, ọdun 2023 ni agbegbe Akari Etiti to wa nijọba ibilẹ Ndokwa East, ipinlẹ Delta to wa layika ile-ẹjọ yii, lasiko ti o n jo nibi ayẹyẹ ibilẹ kan ti pe ni "Afor Day", lo ti ṣe owo Naira to jẹ ẹgbẹrun mẹwaa naira niṣekuṣe, owo naa lo jẹ pe igba naira ni gbogbo rẹ, eyi ti banki CBN gbe jade."
Ọkunrin sọ fun ile-ẹjọ wi pe oun jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an, nigba ti wọn ka a sii leti. Eyi lo si mu ki Agbefọba Francis Jirbo rọ ile-ẹjọ lati ju sẹwọn bo ti tọ.
Ṣugbọn ṣa, agbẹjọro to duro fun Young rọ ile-ẹjọ lati boju aanu wo o, nitori pe ọkunrin naa ti mọ ẹṣẹ rẹ, o si ti kabamọ.
Onidajọ Olubanjo wa ju Young sẹwọn oṣu mẹfa, tabi ko lọ san idaji miliọnu kan naira gẹgẹ bi owo itanran lati rọpo ẹwọn rẹ.

No comments:
Post a Comment