L'Ọjọru ọsẹ yii ni ẹgbẹ to n ṣatilẹyin fun Gomina AbdulRazaq nipinlẹ Kwara, AbdulRahman AbdulRazaq Legacy Advocates (AALA), ti fi itan tuntun balẹ.
Ọjọ naa ni wọn ṣagbekalẹ eto idanilẹkọọ ọlọdọọdun fun ti aawẹ Ramadaani ati Lẹnti, lati mu irẹpọ ba ẹsin Musulumi ati Kristẹni nipinlẹ naa.
Awọn alakoso ẹgbẹ yii niluu Aran-Orin, ijọba ibilẹ Irepodun ni wọn ṣagbekalẹ eto naa, akọkọ iru rẹ to waye ninu gbọngan ilu Aran-Orin.
Imaamu agba niluu naa, Imaamu Tijani Suleiman Ajide, ati alaga ẹgbẹ ẹlẹsin Kristẹni, CAN, Oluṣọ Aguntan T. O. Arowolo, ni wọn ṣe iwaasu lati maa gbe ifẹ leke ni gbogbo igba.
Nibẹ ni wọn ti lo anfaani naa lati gbadura fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq.
Olori ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa, Ọnarebu Salihu Yakubu Danladi, ti ọlọpaa ile igbimọ naa, Ọnarebu Abdulganiyu Gabriel Abolarin ṣoju fun, lo lewaju awọn agba oloṣelu to wa nibi akanṣe eto naa.
Akewejẹ Olayinka Fafoluyi to ṣagbatẹru eto ọhun wa gbe oṣuba kare fun gbogbo awọn akopa, paapaa ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC.
No comments:
Post a Comment