L'opin ọsẹ to kọja yii, ọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Kẹta, ọdun 2206 ni aṣekagba ayẹyẹ ọdun Lisabi Agbongbo Akala waye niluu Abẹokuta tii ṣe olu-ilu ipinlẹ Ogun.
Oniruuru eto alarambara lo waye nibi ayẹyẹ naa to waye ninu ọgba aafin Alake ilẹ Ẹgba, Ọba Adedotun Aremu Gbadebo to wa ni Ake niluu Abẹokuta.
Ọpọ awọn ileeṣẹ lo ṣagbatẹru eto naa, ti ileeṣẹ Adron Homes naa si wa lara wọn..
Ninu gbogbo awọn ileeṣẹ ọhun, Adron Homes nikan lo gbarada laaarin gbogbo wọn, pẹlu bi wọn tun ṣe fi ẹbun owo tọrẹ fun awọn akopa ninu idije ti wọn gbe kalẹ.
Bi awọn eeyan ṣe jẹ ẹbun miliọnu kan naira, bẹẹ lawọn miran jẹ ẹbun ẹgbẹrun lọna ẹẹdẹgbẹta naira, ti awọn miran si jẹ ẹbun ẹgbẹrun lona igba ataabọ naira.
Diẹ ree lara awọn aworan bi ileeṣẹ Adron Homes ṣe ṣe bẹbẹ.
No comments:
Post a Comment