"Oloore Nla ni" - Akewejẹ Fafoluyi fi imọriri nla han si Gomina AbdulRazaq ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, March 31, 2026

"Oloore Nla ni" - Akewejẹ Fafoluyi fi imọriri nla han si Gomina AbdulRazaq ni Kwara


Amugbalẹgbẹ pataki fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara lori eto iroyin igbalode Akewejẹ Olayinka Fafoluyi ti fi idunnu rẹ han si gomina lori anfaani manigbagbe to fun un.

"Yoo wu mi lati fi idunnu ọkan mi han si baba mi, Ọlọlajulọ, Gomina AbdulRahman AbdulRazaq fun ifẹ rẹ to fi han si mi, ati ipa to jọju to ti ko ninu idagbasoke mi lati ọdun pipẹ sẹyin," wọnyi ni Fafoluyi fi bẹrẹ ọrọ idupẹ rẹ.

"Ati si gbogbo eeyan to ṣe abẹwo, ti wọn pe mi, ati awọn to fi atẹjiṣẹ ranṣẹ si mi lasiko ayẹyẹ ọjọ ibi mi. Eyi ni lati fi to o yin leti pe mo mọ riri ifẹ ti ẹ fi han si mi, nko si le gbagbe rẹ.

"Mo tun fi tọkantọkan dupẹ lọwọ alaga ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) nipinlẹ Kwara, Ọmọọba Sunday Fagbemi fun atẹjiṣẹ rẹ, pẹlu gbogbo awọn ẹgbẹ ati ajọ to fi ifẹ han. Mo fẹ ki ẹ mọ pe ifẹ ti ẹ fi han jọ mi loju gidi."

Akewejẹ ko tun ṣai fi imọriri rẹ han si gbogbo alaga ijọba ibilẹ ni Kwara, awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ naa, to fi mọ awọn agbaagba oṣelu ati awọn to di ipo oṣelu mu nipinlẹ naa.

Siwaju sii lo tun gbe oṣuba kare fawọn ọba alaye ati awon agba oṣelu nijọba ibilẹ Irepodun.

Ju gbogbo rẹ lọ, Fafoluyi wa fi idunnu nla han si Adẹdaa to fun lanfaani lati wa laye ni alaafia ati ifọkanbalẹ ọkan.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI