Lojuna lati mu ẹdinku ba aisan jẹjẹrẹ to maa n ba ọpọ awọn obinrin finra, gbajugbaja ileeṣẹ Lafarge to n ṣe simẹnti nilẹ Afrika ti tọwọ bọwe adehun pẹlu ileeṣẹ Leadway Health lati ṣayẹwo ọmu ọfẹ f’awọn obinrin.
Eyi lo wa lara agbekalẹ eto ti wọn la kalẹ fun ti ayajọ awọn obinrin lagbaye, ti ọdun 2026 to waye kọja lọ.
Ọjọbọ, ọsẹ to kọja yii la gbọ pe eto ọhun waye nile iwosan alabọde Akerele to wa lagbegbe Surulere nipinlẹ Eko.
Gẹgẹ bi atẹjade ti awọn alakoso ileeṣẹ Lafarge fi sita, wọn jẹ ko di mimọ pe ohun to ṣe pataki ni lati tete ṣakiyesi aisan naa ni ara, ki itọju rẹ too pẹ ju, debi pe ko ni fẹẹ gba itọju mọ.
Nibi eto naa ni awọn akọṣẹmọṣẹ lẹka eto ilera ti ṣe idanilẹkọọ nipa awọn ohun to n ṣokunfa aisan jẹjẹrẹ lara, paapaa ni ọmu awọn obinrin, ati ọna ti wọn le gba late dẹkun rẹ.
“Ni ileeṣẹ Lafarge Africa, ṣiṣe irolagbara ti kọja agbekalẹ anfaani; o tun jẹ ọna lati daabo bo eto ilera ati igbayegbadun. Nipa mimu anfaani eto ilera to dara wa ni arọwọto awọn araalu, a yọ awọn odi to le dena awọn obinrin lati me le tete ri itọju. Afojusun wa ni pese ọna abayọ ọlọjọ pipẹ nipa fi fun awọn obinrin ni anfaani si eto ilera agbaye, ti wọn yoo si pin imọ naa si agbegbe wọn,” awọn alakoso naa sọ bẹẹ.
Nigba to n sọrọ, Gabriel Pollyn to jẹ alakoso ẹka to n ri si eto ironilagbara nileeṣẹ Lafarge jẹ ko di mimọ pe agbekalẹ naa ni lati di alafo to wa laarin iroyin ati anfaani si eto ilera, nipa ṣiṣe awọn ohun ti yoo jẹ ki awọn obinrin jẹ gaba lori eto ilera ara wọn.
Dokita Olukẹmi Albert-Udoh, Dokita Atẹrẹ Abisọla, ati Adetoro Baiyewu, ni wọn gba awọn obinrin lamọran lati mu ọrọ eto ilera wọn lọkunkundun, ki wọn si ma ṣe bo ẹnu nigba ti wọn ba ṣakiyesi ohunkohun ni agọ ara wọn.
.jpeg)
No comments:
Post a Comment