Busọla Arẹgbẹṣọla
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun ti sọ pe awọn ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lati mọ iru iku to pa ọdọmọbinrin Victoria Ariyọ to n ṣe agunbanirọ rẹ nijọba ibilẹ Guusu Abẹokuta, ipinlẹ naa.
Agbẹnusọ ọlọpaa, Oluṣeyi Babaṣeyi lo fidi rẹ mulẹ ninu atẹjade to fi sita laipẹ yii, to si jẹ ko di mimọ pe iku agunbanirọ naa ko nii lọ lasan.
Bo tilẹ jẹ pe titi di asiko ti a pari akojọpọ iroyin yii, la ko tii le fidi rẹ mulẹ, ṣugbọn ṣa ohun ti a gbọ ni pe ọmọbinrin naa padanu ẹmi rẹ lẹyin ti wọn lo lọ ṣẹ oyun inu rẹ.
A gbọ pe lẹyin ọjọ diẹ to lọ yọ oyun airotẹlẹ to ni, ni ọrọ yiwọ mọ ọn lọwọ, to si gbabẹ sọda sọrun alakeji.
Itẹku to wa ni Kọbapẹ, loju ọna marosẹ Abẹokuta si Ṣagamu ni wọn pada sin ọmọbinrin agunbanirọ naa si pẹlu ibanujẹ.
Ko tii ju oṣu kan lọ, ti wọn sọ pe agunbanirọ kan ti wọn pe orukọ rẹ ni Adelẹyẹ Mary jade laye, ti iku rẹ si n jẹ kayeefi fun ọpọ eeyan, ti Ariyọ naa tun dagbere faye.
Ileeṣẹ amohunmaworan kan to wa nijọba ibilẹ Guusu Abẹokuta yii kan naa la gbọ pe Adelẹyẹ ti n sin orileede baba rẹ, ki ọlọjọ too de lojiji, ti ko si tii sẹni to le sọ pato ohun to ṣokunfa iku rẹ.
Ohun to n jẹ kayeefi fun ọpọ awọn eeyan ni pe ọrẹ timọtimọ ni awọn oloogbe mejeeji yii jẹ, ko to di pe wọn tun pada gba ekuru jẹ lọwọ ẹbọra.
Ọkan lara awọn to mọ nipa awọn mejeeji yii daadaa sọ pe inu yara ni Mary ku si.
“Obinrin akọkọ, Mary lo ku sinu ile rẹ ti ko jinna sibi ti wọn ti n ṣe idanilẹkọọ PPA. Wọn ri oku rẹ ninu yara, ti ko tii sẹni to le sọ pato ohun to ṣokunfa iku rẹ titi di asiko yii.
“Ṣugbọn ṣa, Victoria ti wọn si lọjọ Iṣẹgun, ọsẹ to kọja lo dagbere faye lori wahala oyun to lọ ṣẹ.
“A gbọ pe awọn alakoso ajọ agunbanirọ ti gbe ọrẹkunrin to fun Victoria loyun, ko to lọ yọ, to si ti wa lahaamọ ọlọpaa ni olu ileeṣẹ wọn to wa ni Eleweran niluu Abẹokuta,” ẹni naa sọ bẹẹ.
Nigba to n sọrọ, Oluṣeyi Babaṣeyi to jẹ agbẹnusọ fidi rẹ mulẹ pe lotitọ ni awọn ti bẹrẹ iṣẹ iwadii lori iku agunbanirọ naa, bo tilẹ jẹ pe ko mẹnuba boya ọwọ ti tẹ afurasi.
“Mo le fidi rẹ mulẹ pe iwadii ti n lọ lori iku Victoria Ariyọ, ati pe ẹka ti n ri si iwadii ọran lo gba iṣẹ iwadii naa ṣe,” Babaṣẹyi sọ bẹẹ.
Ṣugbọn sibẹ, agbẹnusọ ajọ agunbanirọ, Ọgbẹni Emmanuel Igba nigba toun naa sọrọ, jẹ ko di mimọ pe oun ko tii gbọ nipa iṣẹlẹ naa, nitori pe oun ko si lẹnu iṣẹ.
O loun ti lọ fun isinmi lẹnu iṣẹ, ati pe inu oṣu Kẹrin, ọdun yii loun yoo pada sẹnu iṣẹ lakọtun.
No comments:
Post a Comment