Ọwọngogo: Gomina Makinde kede afikun ẹgbẹrun mẹwaa naira lori owo oṣu awọn oṣiṣẹ - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, March 23, 2026

Ọwọngogo: Gomina Makinde kede afikun ẹgbẹrun mẹwaa naira lori owo oṣu awọn oṣiṣẹ


Gomina Seyi Makinde tipinlẹ Oyo ti kede afikun ẹgbẹrun mẹwaa naira lori owo oṣu awọn oṣiṣẹ, gẹgẹ bi afikun owo ọkọ ti wọn n wọ lọ si ibi-iṣẹ.

Owo yii ni yoo jẹ gẹgẹ bi owo iranwọ fun awọn oṣiṣẹ ijọba, latari owo epo to lọ soke kaakiri Naijiria.

Alaga ẹgbẹ awọn oṣiṣẹ, ẹka ti Nigeria Labour Congress (NLC), nipinlẹ Oyo, Kọmureedi Kayode Martins, ninu atẹjade to fi sita lọjọ Aje, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Kẹta, ọdun 2026, jẹ ko di mimọ pe ijọba ti gbọ ẹbẹ wọn lati fi owo kun owo ọkọ ti wọn n wọ lọ si ibi iṣẹ.

“Lẹyin ẹbẹ ati lẹta ti ẹgbẹ oṣiṣẹ nipinlẹ Oyo, Nigeria Labour Congress (NLC) kọ, lowurọ yii, ijọba ipinlẹ yii ti fi ẹgbẹrun mẹwaa naira kun owo awọn oṣiṣẹ nipinlẹ yii.

“Afikun owo yii ni yoo bẹrẹ lati inu oṣu Kẹrin, ọdun 2026, leyi ti yoo jẹ iranwọ ati idẹrun fun awọn oṣiṣẹ patapata lẹkọ eto ọkọ wiwọ, eyi to ko ipenija ba eto ọrọ aje.

“Idagbasoke yii lo waye lẹyin akiyesi ati ẹbẹ ẹgbẹ NLC, eyi ti a pe lati fi mu iranwọ ba eto iṣẹ ijọba. Ẹkunrẹrẹ nipa bi owo naa yoo ṣe fẹsẹ mulẹ yoo lọ sọdọ awọn alẹnulọrọ laipẹ.”

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI