Nitori egboogi oloro to gbe, wọn ju Adegbitẹ sẹwọn ọdun mejidinlaadoje l’Ekoo - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, March 24, 2026

Nitori egboogi oloro to gbe, wọn ju Adegbitẹ sẹwọn ọdun mejidinlaadoje l’Ekoo

Ṣọla Ogunlana

Ile-ẹjọ giga apapọ to wa nipinlẹ Ekoo ti ju Baale ile, ẹni ọdun mejilelogoji kan, Solomon Adegbitẹ sẹwọn ọdun mejidinlaadoje lori ẹsun gbigbe egboogi oloro.

Orileede Italy lọhun ni wọn sọ pe Adegbitẹ n gbe, ti wọn si ni ko niṣẹ meji ju gbigbe egboogi oloro kaakiri agbaye lọ.

Egboogi oloro Tiramadọ ti iwọn rẹ jẹ kilogiramu kan ati ọgbọn (1.30kg) ni wọn ka mọ Adegbitẹ lọwọ lasiko tọwọ palaba rẹ segi.

Ọjọ kejilelogun, oṣu Keje, ọdun 2025 ni ọwọ tẹ Adegbitẹ lasiko to fẹẹ wọ ọkọ baalu ti Royal Air Maroc, eyi to n lọ si Italy, ti yoo si gba Casablanca lorileede Morocco wọle.

Papakọ ofurufu Murtala Muhammed to wa lagbegbe Ikẹja nipinlẹ Ekoo lọwọ awọn oṣiṣẹ ajọ to n gbogun ti lilo egboogi oloro, NDLEA ti tẹ ẹ.

Inu aṣọ ti wọn pe ni jakẹẹti ti Adegbitẹ wọ la gbọ pe wọn ti ṣawari egboogi oloro naa.

Ṣaaju asiko yii la gbọ pe ko di ni igba mẹta ọtọọtọ ti ọwọ ti tẹ Adegbitẹ, to fi mọ ọdun 2024 ti ọwọ tẹ gbẹyin.

Nigba to n gbe idajọ kalẹ lori ẹsun mẹẹdogun ọtọọtọ ti ajọ NDLEA fi kan an, Onidajọ Musa Kakaki sọ pe awọn ẹri to wa niwaju oun fidi mulẹ, o si kọja ohun ti wọn le fọwọ bo mọlẹ.

Oniodajọ Kakaki sọ pe ki Adegbitẹ lọ fi ẹwọn ọdun mẹẹdogun naa gbara, lai faaye silẹ fun owo itanran.

Ninu idajọ naa, Onidajọ Kakaki sọ pe Adegbitẹ yoo lo ẹwọn ọdun mẹẹdogun lori ẹsun kinni; ẹwọn ọdun mẹẹdogun lori ẹsun keji; ẹwọn ọdun mẹẹdogun lori ẹsun kẹta; ẹwọn ọdun mẹẹdogun lori ẹsun kẹrin; ẹwọn ọdun mẹẹdogun lori ẹsun karun; ẹwọn ọdun mẹẹdogun lori ẹsun kẹfa; ẹwọn ọdun mẹwaa lori ẹsun keje.

Bakan naa lo ni yoo tun lo ẹwọn ọdun mẹrin lori ẹsun kẹjọ; ẹwọn ọdun mẹrin lori ẹsun kẹsan; ẹwọn ọdun mẹrin lori ẹsun kẹwaa; ẹwọn ọdun mẹirn lori ẹsun kọkanla; ẹwọn ọdun mẹrin lori ẹsun kejila, ati ẹwọn ọdun mẹwaa lori ẹsun kẹẹdogun.

Gbogbo awọn ọdun yii ni ile-ẹjọ sọ pe Adegbitẹ yoo lo papọ ni igba kan naa, ti gbogbo ọdun rẹ lọgba ẹwọn yoo si jẹ ọdun mẹẹdogun.

Bakan naa ni ile-ẹjọ tun paṣẹ pe ki ijọba apapọ gbẹsẹ le iwe igbelu orileede Italy ti Adegbitẹ ni, ati iwe irinna Naijiria rẹ, to fi mọ foonu Samsung Galaxy A22, apo aṣuwọn rẹ fun ti ile itaja oogun Aderevico Pharmacy, to fi mọ awọn dukia to wa labẹ akoso ile itaja oogun naa.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI