A ṣetan lati da awọn ile-ẹkọ ijọ pada fun wọn - Gomina Abiọdun ṣeleri - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, April 12, 2026

A ṣetan lati da awọn ile-ẹkọ ijọ pada fun wọn - Gomina Abiọdun ṣeleri


Gomina Dapọ Abiọdun tipinlẹ Ogun ti jẹ ko di mimọ pe iṣakoso oun ti ṣetan lati da awọn ile-ẹkọ to jẹ ti ijọ pada si bi wọn ṣe wa lati ibẹrẹ pẹpẹ fun awọn olori ijọ.

"A n fidi ileri wa mulẹ lati da awọn ile-ẹkọ ijọ to wa nipinlẹ Ogun pada fun awọn yo ni wọn, gẹgẹ bi ipinnu wa ninu ibaṣepọ lẹka eto ẹkọ ati eto ilera," Gomina Abiodun sọ bẹẹ ninu ọrọ to kọ soju opo ayelujara rẹ laipẹ yii.

O tẹsiwaju pe, "A jẹ ki eyi di mimọ lasiko ti a n gba awọn olori ijọ Aposteli (Apostolic Nuncio) wa silẹ Naijiria, Archbishop Michael Francis Crotty, ati awọn olori ijọ Katoliiki pẹlu awọn olori ijọ miran lalejo, nibi a ti jẹ ko di mimọ pe ijọba ko le da ọrọ idagbasoke ṣe."

Bakan naa lo sọ pe oun mọ ipa ti awọn agboole igbagbọ n ko nipa ṣiṣe igbelarugẹ fun eto ẹkọ, ilera, alaafia ati ohun to nii ṣe pẹlu awujọ.

O ni ilẹkun ijọba ṣi silẹ fun ibaṣepọ to dan mọnran pẹlu ijọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI