Gomina AbdulRazaq kẹdun iku awọn aṣọgbo ti wọn pa danu ni Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, April 12, 2026

Gomina AbdulRazaq kẹdun iku awọn aṣọgbo ti wọn pa danu ni Kwara


Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tipinlẹ Kwara ti kọminu lori bi awọn agbebọn aṣekupani ti a mọ si bandiiti ṣe ṣeku pa awọn aṣọgbo niluu Nuku to wa nijọba ibilẹ Kaiama, ipinlẹ naa.

Aṣọgbo marun-un la gbọ pe awọn bandiiti naa ṣe ikọlu ẹsan si laaarin oru ọganjọ.

Nigba to n kẹdun naa, gomina ṣapejuwe awọn aṣọgbo naa gẹgẹ bi akikanju to fi ọkan ṣiṣẹ aabo, ti wọn si fi ẹmi wọn lelẹ loju ogun.

O sọ pe awọn aṣọgbo naa fi ọkan akikanju wọn han lati gbogun ti awọn bandiiti, ti wọn si pa pupọ ninu wọn danu.

Gomina sọ pe iṣẹlẹ naa ṣe apejuwe idunkooko ti awọn bandiiti n ṣe fun awọn ara agbegbe igberiko, to si rọ awọn ileeṣẹ ologun lati dide gbogun ti awọn onigbagbọ buruku naa.

"Mo gbe oṣuba kare fun awọn oṣiṣẹ eleto aabo ni ẹka yii, mo si rọ wọn lati ṣe ju bẹẹ lọ," Gomina AbdulRazaq sọ bẹẹ.

"Ko si ohun ti a le fi mọ riri bi awọn aṣọgbo naa ṣe fi ẹmi wọn lelẹ fun wa. A fi ọrọ ibanikẹdun wa ranṣẹ si awọn mọlẹbi wọn, ati awọn agbegbe wọn. Wọn yoo maa jẹ akọni wa titilai.

Gomina AbdulRazaq wa fidi rẹ mulẹ pe awọn yoo dide iranwọ si awọn mọlẹbi awọn oloogbe naa, bẹẹ lo gbadura ki Ọlọrun tẹ wọn si afẹfẹ rere.

Lẹyin eyi ni gomina yan igbimọ eleto aabo lati ṣagbekalẹ ọna ọtun lori eto aabo, eyi to pe ni "Kwara State Security Strategy Committee".

Awọn igbimọ naa ni wọn jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Kwara ti wọn ti jagun-fẹyinti.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI