Oludije sipo gomina nipinlẹ labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC) nipinlẹ Ọyọ, ninu eto idibo ọdun 2027, Sharafadeen Alli s'awọn agbaagba ẹgbẹ naa ni wọọdu kẹta to wa nijọba ibilẹ Ariwa Ibadan, iyẹn nibi to fẹẹ gba jade.
Alli lo ṣe abẹwo yii lati jẹ ki awọn agbaagba naa mọ erongba rẹ, ṣaaju ko to di pe o kede sita gbangba fun gbogbo eeyan.
Oludije naa lo n ṣoju ẹkun idibo Guusu Ọyọ nile igbimọ aṣofin agba to wa niluu Abuja, labẹ asia ẹgbẹ oṣelu kan naa, APC.
Ọjọ Abamẹta to kọja yii ni Alli ṣabẹwo naa, nibi to ti sọ awọn erongba rẹ lati jade du ipo gomina lọdun 2027, to si n bẹbẹ fun atilẹyin.
Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, abẹwo naa ṣe pataki, to si wa lara ọkan lara igbesẹ fun ikede, ṣaaju ọjọ Ẹti to n bọ yii, nibi ti yoo ti jẹ ki gbogbo ọmọ ati olugbe ipinlẹ Ọyọ mọ ipinnu rẹ lati jade du ipo gomina lọdun 2027.
Agba oloṣelu naa, to tun jẹ Ẹkaarun Balogun nilẹ Ibadan, nigba to n ba awọn eeyan sọrọ, pe fun iṣọkan laaarin gbogbo ọmọ ẹgbẹ, to si ni wiwa ni iṣọkan ṣe pataki lati jẹ ki wọn jawe olubori ninu eto idibo to n bọ naa.
Nibẹ lo tun ti ṣapejuwe ẹgbẹ APC gẹgẹ bii ọkọ to n wa ilọsiwaju ipinlẹ naa lọ siwaju.
O jẹ ko di mimọ pe adari to ṣee fọkan tan, loun yoo jẹ nigba toun ba de ipo gomina toun n foju sọna fun, toun ko si nii jinna si gbogbo ọmọ ẹgbẹ.

No comments:
Post a Comment