Fayoṣe lo ke gbajare yii ninu ọrọ to kọ soju opo ayelujara ti 'X' lọjọ Aiku, ọjọ kejila, oṣu Kẹrin, ọdun 2026.
Ọkunrin naa sọ pe olobo kan ti tẹ oun lọwọ pe Gomina Makinde yoo kọ iwe ifẹsunkan nipa Olubadan lọsẹ tuntun ti a ṣẹṣẹ wọ yii.
Fayoṣe sọ pe oniruuru ẹsun ni Makinde yoo fi kan Ladọja ninu iwe ti yoo kọ ranṣẹ sii, lori erongba lati wa ọna fun irọ loye rẹ.
Ninu ọrọ to kọ naa, o sọ pe, “Mo gbọ daadaa wi pe GOmina Ṣeyi Makinde tipinlẹ Ọyọ ti bẹrẹ igbesẹ lati rọ Olubadan ilẹ Ibadan, Ọba Raṣhidi Adewọlu Ladọja loye rẹ.
“Igbesẹ iditẹ naa yoo bẹrẹ l'ọsẹ yii, nitori pe ijọba yoo kọ iwe ẹsun lodi si Olubadan, nibi ti wọn yoo ti fẹsun kan an nipa idi ti ko fi yọju sibi ifinijoye awọn ọba ilẹ Ibadan lọsẹ meji sẹyin, ati awọn oniruur ẹsun miran.
“Fun awa ni ti wa, awa yoo maa wo 'Ṣìgìdì Ṣeyi Makinde tó fẹ́ ṣe eré ẹ̀tẹ́'”.

No comments:
Post a Comment