Ogogo tu aṣiri idi ti ko fi da sọrọ Funke Akindele ati Toyin Abraham - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, April 3, 2026

Ogogo tu aṣiri idi ti ko fi da sọrọ Funke Akindele ati Toyin Abraham


Agba oṣere ilẹ wa nni, Alaaji Taiwo Hassan tọpọ awọn eeyan mọ si Ogogo ti sọ awọn idi pataki ti ko fi si ọrọ aawọ to n ṣẹlẹ laaarin awọn oṣerebinrin meji nni, Funke Akindele ati Toyin Abraham.

Ogogo lo sọrọ naa nibi ifọrọwerọ to ṣe nileeṣẹ amohunmaworan ori ayelujara ti 'Feel Right TV'.

Fun awọn to ba mọ ohun to ṣẹṣẹ ṣẹlẹ laaarin awọn oṣebinrin meji naa, wọn yoo mọ pe ọjọ Aiku to kọja yii ni ija wọn tun gbọna miran yọ.

Toyin lo de ibi eto ifilọlẹ fiimu agbelewo tuntun ti Iyabọ Ojo ṣẹṣẹ fẹẹ gbe jade, iyẹn Arinzo, to si ki awọn to wa nibẹ. Loju ẹsẹ lo ti ki Funke Akindele, ṣugbọn tiyẹn ko ṣebi ẹni to rii rara.

Latigba naa ni oniruuru awuyewuye ti n lọ lori ayelujara. Bi awọn kan ṣe n bu ẹnu atẹ lu Toyin, bẹẹ lawọn miran n bu ẹnu atẹ lu Funke.

Nigba to n sọrọ, Ogogo sọ pe ọrọ awọn obinrin ṣoro lati da si, ki wọn ma ba a f'ori eeyan fọ agbọn.

O sọ pe asiko ree to yẹ ki awọn mejeeji maa dupẹ lọwọ Ọlọrun fun awọn nnkan ti wọn ti ni, ati ipo ti wọn wa lonii.

Agba oṣere naa jẹ ko di mimọ pe ọkunrin ti ko ba gbọn lo maa da sọrọ awọn obinrin”.

“Emi kii da sọrọ aawọ to ba n ṣẹlẹ laaarin awọn obinrin. Awọn mejeeji ni Ọlọrun ti kẹ. O dara, ki ni idi ti awọn mejeeji fi n ja? Nigba ti awọn ọkunrin ba n ja lori ohun to n fa ija awọn eeyan yii, ẹrin ni wọn maa fi rin, ṣugbọn niṣe ni awọn obinrin yoo tutọ soke, ti wọn maa foju gba a. Fun idi eyi, o ṣoro lati da si”, Ogogo sọ bẹẹ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI