Ijọba Kwara tun bẹrẹ atunṣe ile-ẹkọ mọkanlelaadọfa labẹ eto AGILE - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Friday, April 3, 2026

Ijọba Kwara tun bẹrẹ atunṣe ile-ẹkọ mọkanlelaadọfa labẹ eto AGILE


Ijọba ipinlẹ Kwara labẹ iṣakoso Gomina AbdulRahman AbdulRazaq tun ti bẹrẹ akanṣe eto igbalode lawọn ile-ẹkọ to wa kaakiri ipinlẹ naa.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ile-ẹkọ mọkanlelaadọfa (111) to wa kaakiri gbogbo ipinlẹ naa ni yoo gba atunṣe labẹ akanṣe eto ti wọn pe ni Adolescent Girls Initiative for Learning and Empowerment (AGILE) Project ati School-Based Management Committees (SBMCs) .

Eto yii la gbọ pe yoo fun ijọba lanfaani lati ṣe atunṣe si ọpọ awọn ile-ẹkọ ti wọn ti dẹnukọlẹ.

Nibi eto ilanilọyẹ to waye laipẹ yii niluu Ilorin, Ọmọwe Lawal Olohungbebe jẹ ko di mimọ pe erongba ijọba ni lati jẹ ki eto ẹkọ ati yara ilẹkọọ figagbaga pẹlu awọn akẹgbẹ wọn lagbaye.

Ọmọwe Olohungbe fidi rẹ mulẹ pe ile-ẹkọ girama 898 ni ijọba n fonu sọna fun lati fun idagbasoke ba.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI