O ma ṣe o! Gbajumọ oṣere, Patrick Doyle padanu ọmọ to ṣẹṣẹ bi - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Sunday, April 12, 2026

O ma ṣe o! Gbajumọ oṣere, Patrick Doyle padanu ọmọ to ṣẹṣẹ bi


Asiko yii kii ṣe asiko to dara rara fun gbajugbaja oṣere ilẹ Naijiria nni, Patrick Doyle, pẹlu bo ṣe kede ipapoda ọmọ tuntun ti iyawo rẹ ṣẹṣẹ bi, Omayinuwa Harriet.

Gbajumọ oṣere naa lo fi iroyin ọhun lede loju opo Facebook rẹ ni deedee agogo mẹrin kọja iṣẹju mẹẹdogun, ọjọ Aiku, ọjọ kejila, oṣu Kẹrin, ọdun 2026.

Doyle nigba to n fi ibanujẹ sọrọ, sọ pe ọjọ keji ti iyawo oun bimọ naa, lo pada sajule ọrun.

“Omayinuwa ṣabẹwo rampẹ si wa ni deedee agogo mọkanla ku ogun iṣẹju ọjọ Ẹti, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹrin, to si pada si ọrun lọjọ Satide, ọjọ kọkanla, oṣu Kẹrin, ni nnkan bi agogo mẹrin kọja iṣẹju mẹẹdogun,” ọkunrin naa kọ ọrọ yii sita.

O tun tẹsiwaju pe, “Wiwa rẹ ko pẹ rara, bo tilẹ jẹ pe ayọ lo mu wa. Yoo wu wa lati duro pẹ, ṣugbọn ṣa, erongba ọrun yatọ si ti wa.

“Ohun ti a mọ daju ni pe Ọlọrun lo n dari irin ọmọ eniyan. Igbagbọ wa ninu ohun rere Ọlọrun la ṣi duro le lori lai wo ohunkohun. Sibẹ’ sibẹ’ Oluwa n’bẹ’. Yoo dara fun ọkan wa,” o sọ bẹẹ.

Iroyin to tẹ wa lọwọ jẹ ko di mimọ pe iyawo kẹta ti Doyle fẹ, Funmilayọ lo bi ọmọbinrin tuntun naa to jade laye.

Bi ẹ ko ba gbagbe, kete ti Funmilayọ bimọ naa tan, ni agba oṣere naa kede sita, to si jẹ ko di mimọ pe iya ati ọmọ wa ni alaafia, lai mọ pe ọrọ yoo pada yiwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI