Nitori ọdun Ileya, Adron Homes ṣagbekalẹ anfaani ọtun fawọn onibara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, April 13, 2026

Nitori ọdun Ileya, Adron Homes ṣagbekalẹ anfaani ọtun fawọn onibara


Ileeṣẹ Adron Homes tun ti ṣe bẹbẹ nipa gbigbe anfaani ọtun ti ko wọpọ kalẹ fun gbogbo awọn onibara wọn kaakiri agbaye, paapaa bi ayẹyẹ ọdun Ileya ṣe n sunmọ etile.

Gẹgẹ bi atẹjade ti awọn alakoso ileeṣẹ naa fi sita lọjọ Aje, ọsẹ yii, wọn jẹ ko di mimọ pe anfaani ida ọgbọn lo wa lori gbogbo dukia wọn patapata kaakiri Naijiria.

Bi ayẹyẹ ọdun Ileya ṣe n sunmọ etile, ileeṣẹ Adron Homes & Properties, to n lewaju lẹka eto ile gbigbe nilẹ Naijiria, ti bẹrẹ anfaani ọtun ti Ileya, eyi ti a pe ni 'Sallah Mega Promo', a ṣe agbekalẹ rẹ lati jẹ ki awọn onibara wa jẹ anfaani sisan owo diẹdiẹ ati ẹdinwo ti ko wọpọ, pẹlu awọn ẹbun to jọju, awọn alakoso naa sọ bẹẹ.

Wọn sọ siwaju pe fun igba diẹ ni anfaani naa yoo fi wa nita, lojuna lati ro awọn ọmọ Naijiria lagbara, ki wọn le ṣajọyọ ọdun naa ninu idunnu ati ayọ, nipa didooko lori ogun ọjọ iwaju ti yoo lalopẹ.

Awọn onibara wa yoo jẹ anfaani ida ọgbọn lori pulọọti ilẹ kan kaakiri ileeṣẹ Adron Homes to wa nilẹ Naijiria, pẹlu anfaani sisan owo fun oṣu mẹrindinlogoji (36 months). Ni afikun, awọn onibara tun le lo oṣu mẹrin lati san owo akọkọ-san wọn, lati le jẹ ko rọrun fun wọn.

“Ileya jẹ asiko ififunni, irubọ ati ajọyọ. Ni ileeṣẹ Adron Homes, a nigbagbọ pe ko si asiko to dara lati ro awọn mọlẹbi ati oludokoowo lagbara nipa anfaani lati ni ilẹ, ki wọn si tun gba ẹbun to jọju.”

Oniruuru ẹbun bii Bagai irẹsi, ororo, ohun jijẹ ọmọde (Noodles), ewurẹ ati awọn ohun elo ile loriṣirṣi lo wa nilẹ f'awọn onibara naa.

Fun alaye lẹkunrẹrẹ tabi ibeere:
📲 WhatsApp: +234 805 101 1951

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI