Gbajugbaja oṣere ti irawọ rẹ n tan lasiko yii, Tobi Makinde ti jẹ ko di mimọ pe ko ija kankan tabi gbolohun asọ to waye laaarin oun ati Funkẹ Akindele.
Ọmọkunrin naa sọ pe oun ko mọ igba ti aawọ waye laaarin oun ati gbjumọ oṣere naa, ati pe ibaṣepọ awọn ko bẹrẹ lori ayelujara, bẹẹ si ni ko le d'opin lori ayelujara.
Laipẹ yii ni iroyin naa jade sori ayelujara wi pe Funkẹ tọpọ mọ si Mama Tobi lagboole oṣere, lo kọ lati yọju sibi ayẹyẹ igbeyawo rẹ to waye ninu oṣu Kejila, ọdun 2025.
Nigba to n ba BBC sọrọ, Makinde sọ pe awọn eeyan lori ayelujara ni wọn maa n ohun ti ko sọnu kaakiri, ati pe irọ to jinna si otitọ ni wọn maa n gbe kaakiri.
Ninu ọrọ rẹ, o sọ pe “Nko ranti igba kankan ti aawọ wa laarin ẹmi ati Iya Funkẹ. Ko s'ohun to ṣẹlẹ. Ibaṣepọ wa ko bẹrẹ lori ayelujara, bẹẹ si ni ko le d'opin lori ayelujara.
“Bi a ṣe n dagba, ti a n lo lati ipele kan si ipele miran, awọn ibaṣepọ kan le dabi ẹni wi pe wọn ti sọnu sinu ọkọ.”

No comments:
Post a Comment