Akewejẹ Fafoluyi gba fọọmu ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kwara - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Saturday, May 2, 2026

Akewejẹ Fafoluyi gba fọọmu ọmọ ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kwara


Lọjọ Iṣẹgun, ọsẹ yii ni Akewejẹ ilu Aran-Orin, Oloye Olayinka Fafoluyi tọpọ awọn eeyan tun mọ si Solace gba fọọmu lati dije du ipo ile igbimọ aṣofin ipinlẹ Kwara labẹ asia ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress (APC), ninu eto idibo to n bọ lọdun 2027.

Akewejẹ gba fọọmu naa ṣaaju eto idibo abẹle ti yoo waye logunjọ, oṣu Karun-un, ọdun 2026 ti a wa yii.

Gẹgẹ bi a ṣe gbọ, ẹkun idibo Irepodun ni Solace, ẹni to tun jẹ amugbalẹgbẹ pataki fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lori eto iroyin igbalode fẹẹ ṣoju nile igbimọ naa.

Bi ẹ ko ba gbagbe, Ọjọbọ, ọgbọn ọjọ, oṣu Kẹrin ni ọknrin naa fi erongba rẹ han fun gbogbo awọn alẹnulọrọ lẹgbẹ oṣelu APC, paapaa awọn araalu.

Gbọngan ilu Aran-Orin to wa nijọba ibilẹ Irepodun ni eto naa ti waye, nibi ti awọn eeyan ti ṣeleri lati ṣatulẹyin fun un.

Fọọmu ti Akewejẹ gba yii, lo fi aridaju lelẹ pe ọkunrin naa ti ṣetan lati mu eto oṣelu awarawa dele-doko.

O wa rọ awọn ọmọ ẹgbẹ lati dide atilẹyin foun lasiko eto idibo abẹle, ki ipo naa le ja mọ oun lọwọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI