Pẹlu idunnu ati ayọ lawọn ọba alaye mẹta ọtọọtọ nijọba ibilẹ Irepodun nipinlẹ Kwara fi ṣadura fun Akewejẹ tiluu Aran-Orin, Oloye Olayinka Fafoluyi tọpọ awọn eeyan tun mọ si Solace.
Akewejẹ, ẹni to tun jẹ amugbalẹgbẹ pataki agba fun Gomina AbdulRahman AbdulRazaq lori eto iroyin igbalode lo fẹẹ jade du ipo ọkan lara awọn ọmọ ile igbimọ aṣofin nipinlẹ naa, lasiko eto idibo ọdun 2027 to n bọ lọna.
Alaran tiluu Aran-Orin, Ọba Joseph Oyeweyipo Babalola; Onipetu tiluu Ipetu Igbomina, Ọba Samuel Olabanji Olanrewaju Erinfolami; ati Onirore tiluu Rore, Ọba Ezekiel Olawale Oyewole lawọn ori ade naa ti wọn fi idunnu ṣadura aṣeyọri fun un.
Ọjọ Abamẹta, oni, ni Solace ṣabẹwo si aafin Alaran tiluu Aran-Orin, Ọba Babalola, nibi to ti lọ fidi rẹ mulẹ pe oun ti gba fọọmu lati jade du ipo aṣofin ti yoo ṣoju awọn agbegbe mẹta, Aran-Orin, Rore ati Ipetu nijọba ibilẹ Irepodun.
Yatọ si awọn ọba alaye mẹta naa to wa nibi akanṣe abẹwo ọhun, awọn agba oloye ati alẹnulọrọ lawọn agbegbe yii ko gbẹyin nibẹ, ti awọn naa si fi tọkantọkan ṣe adura, pẹlu ileri atilẹyin titi de opin.
Nigba to n ṣe adura, Kabiyesi sọ pe “Ko ṣee ṣe ki eeyan ma ni ọta, ṣugbọn wa maa bori wọn, Ọlọrun yoo si ṣe ohun gbogbo to nii ṣe pẹlu rẹ laṣepe.”
Siwaju sii ni Akewejẹ ṣeleri lati sa gbogbo ipa ati agbara oun lati rii pe awọn ara agbegbe naa jẹ mudunmudun eto oṣelu awa-ara-wa, bi wọn ba gbe oun de ipo naa.

No comments:
Post a Comment