Akewejẹ Fafoluyi lo ṣeto iranwọ yii lasiko abẹwo to ṣe kaakiri wọọdu to wa nijọba ibilẹ Irepodun, paapaa ni wọọdu keji ti agbegbe Oro.
Nibẹ ni amugbalẹgbẹ pataki naa ti jẹ ko di mimọ pe awọn Opo ati arugbo ti ko din ni ọgọrun mẹrin ni yoo jẹ anfaani eto iranwọ naa kaakiri ijọba ibilẹ Irepodun.
Akewejẹ to n jade du ipo aṣofin ipinlẹ naa lati ṣoju awọn ara agbegbe naa fidi rẹ mulẹ pe awọn Opo ati arugbo ni yoo jẹ anfaani naa.
Ẹgbẹrun mẹwaa naira la gbọ pe awọn eeyan jẹ anfaani rẹ, iyẹn awọn Opo ati arugbo aadọta to wa nibẹ.
Nigba ti wọn n gba Akewejẹ naa lalejo, awọn alẹnulọrọ, agbaagba lẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, to fi mọ awọn olulufẹ rẹ ni wọn gbe oṣuba kare fun un.
Nigba to n sọrọ, Akewejẹ ṣalaye ni kikun nipa awọn erongba ati afojusun rẹ nigba to ba de ipo aṣofin.
O wa rọ wọn lati dide atilẹyin foun lasiko eto idibo apapọ ọdun 2027, to si ṣeleri lati jẹ ki wọn ni anfaani si eto iṣejọba tiwantiwa.
No comments:
Post a Comment