Ẹ dẹkun rumọọsi, ijọba Kwara ko na biliọnu kan naira lati fi ṣe afara Moro - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, May 4, 2026

Ẹ dẹkun rumọọsi, ijọba Kwara ko na biliọnu kan naira lati fi ṣe afara Moro


Ileeṣẹ to n ri sọrọ akanṣe iṣẹ nipinlẹ Kwara ti sọ pe ko si otitọ kankan ninu iroyin ti wọn n gbe kaakiri nipa wi pe ohun fi biliọnu kan naira ṣe afara Moro.

Afara Moro lo so opopona ipinlẹ Kwara papọ mọ ti ipinlẹ Oyo

Ninu atẹjade ti ileeṣẹ naa fi sita lọjọ Aiku to kọja yii, ni wọn ti bu ẹnu atẹ lu fọnran kan ti ẹnikan ti wọn pe orukọ rẹ ni Ajibare Talks, eyi ti wọn lo fi n tako ijọba ipinlẹ naa.

"Gẹgẹ bi ijọba to n tete dide sọrọ to ba ṣe koko, oju ẹsẹ ni ijọba ti maa n dide si ohunkohun to le pa araalu lara, lai nii ṣe pẹlu pe boya iṣẹ akanṣe naa jẹ ti ijọba apapọ, eyi to jọ bii ti afara Moro," atẹjade naa sọ bẹẹ.

Ijọba sọ pe iṣẹ atunṣe ti wọn ṣe lori afara naa ko na wọn ju miliọnu mẹtadinlọgbọn pere lọ, ati pe lati le jẹ fun lilo fun igba diẹ ni wọn ṣee fun, bo tilẹ jẹ pe ijọba apapọ ti bẹrẹ iṣẹ afara tuntun miran.

"Ko si igba kankan labẹ iṣakoso yii, ti ileeṣẹ to n ri sọrọ akanṣe iṣẹ tabi ẹka ileeṣẹ kankan na biliọnu kan le diẹ (₦1.2 b) lori atunṣe bẹẹ."

Wọn ni agbelẹrọ lasan ni iroyin ọhun jẹ, ati pe erongba lati ba Ọnarebu Abdulquawiy Olododo lorukọ jẹ ni.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI