Ẹ dakẹ rumọọsi, ko si idajọ kankan to waye lori ipo Olu tiluu Warewa nipinlẹ Ogun - Awọn oloye ilu pariwo sita faraye - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Monday, May 11, 2026

Ẹ dakẹ rumọọsi, ko si idajọ kankan to waye lori ipo Olu tiluu Warewa nipinlẹ Ogun - Awọn oloye ilu pariwo sita faraye


Igbimọ awọn Oloye ilu Warewa, ni'jọba Ibilẹ Ifo, ni'pinlẹ Ogun ti sọ ọ di mimọ pe irọ t'o jina s'ootọ ni iroyin kan t'awọn eeyan kan n gbe kiri igboro pe Ile-ẹjọ giga to fi'ka'le si'luu Abẹokuta, ni'pinlẹ Ogun ti da ẹjọ t'o nii ṣe pẹlu Ori Apeere Olu ti'luu Warewa, nijọba Ibilẹ Ifo, ni'pinlẹ Ogun.  

Igbimọ yii tẹ'nu mọ-ọn pe ọrọ t'o n lọ ni'gboro lori ẹjọ ọhun ti suiti nọmba ẹ jẹ AB/696/2023 jẹ iroyin ẹlẹjẹ tabi ofege tawọn eeyan ko gbọdọ kakun rara, nitori pe Ile-ẹjọ ti igbẹjọ naa wa ko ti i da ẹjọ yii. 

Ninu atẹjade tawọn oloye ilu Warewa f'ọwọ si ni wọn ti sọ pe awọn to wa nidii iroyin ẹlẹjẹ yii kan-an fẹẹ da ilu ru lasan ni, bẹẹni wọn ṣe eyi lati tan awọn araa'lu, nitori wipe irọ funfun balau lohun ti wọn n gbe kiiri yii, bẹẹni wọn rọ awọn araalu lati ma ṣe tẹ'ti si'ru iroyin agbe'lẹ rọ yii.  

Atẹjade naa tẹsiwaju bayii pe suiti naa ti wọn pe ni Rev. Ibikunle Oluwọle Johnson at'awọn yooku si wa niwaju adajọ, ti idajọ ko ti i waye lori ẹ, eyi to tako ohun tawọn kan n gbe pooyi ẹnu lati ṣi awọn araa'lu lọna.

Igbimọ awọn oloye yii fi kun ọrọ wọn pe bo tilẹ jẹ pe ile-ẹjọ naa kọkọ ti da a pe lati ta ko iyansi'po Alaiyeluwa Ọba Hakeem Balogun gẹgẹ bii Olu ti'luu Warewa, lojuẹsẹ ni a a ti tako ohun ti Ile-ẹjọ yii sọ ti a si gbe igbesẹ lati gba Ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun lọ, bẹẹ la beere fun pe ki Alayeluwa si wa lori apeere awọn baba nla wọn ki igbẹjọ ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun t'o o wa'ye. 

Igbimọ awọn oloye ni igbesẹ lati yo Kabieesi nipo ṣaaju idajọ ile-ẹjọ kotẹmilọrun ko ba ofin mu rara.  

Bakan naa lawọn Oloye yii fi kun ọrọ wọn pe Olùjẹ́'jọ́ kẹrìnlá ní'nú ẹjọ́ náà ti tẹ̀lé gbogbo ohun tí ilé ẹjọ́ pa láṣẹ látì'gbà tí wọ́n ti dá'jọ náà, èyí tí wọ́n lo fihàn pé o bọ̀wọ̀ fún ilé ẹjọ́ àti ìgbẹ́kẹ̀lé pé idajọ ododo yoo waye.

Awọn Oloye yii waa rọ t'oni'le-t'alejo niluu Warewa lati ma fo'ya, ki wọn bọwọ fun Ofin, ki wọn si maa gbe igbe alaafia titi di'gba ti ida'jọ Ile-ẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun yoo wa'ye.

Ni'pari ọrọ wọn, wọn rọ gbogbo awọn ọmọ bibi ati olugbe Ilu Warewa lati ma ṣe tẹ'ti si iroyin ẹlẹjẹ yii, ki wọn si maa ba iṣẹ wọn lọ ni alaafia.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI