Awọn akẹkọọ Kwara fakọyọ pẹlu ipo keji nilẹ Afrika - IROYIN AWIKONKO

LÉRÉFÈÉ

Tuesday, May 12, 2026

Awọn akẹkọọ Kwara fakọyọ pẹlu ipo keji nilẹ Afrika


Awọn akẹkọọ ile-ẹkọ lati ipinlẹ Kwara ti wọn lọ ṣoju ilẹ Naijiria nibi idije ifigagbaga awọn akẹkọọ nilẹ Adulawo lo ṣe ipo keji.

Ile-ẹkọ ti ko din ọgọrun ile-ẹkọ kaakiri orileede mejila nilẹ Afrika ni wọn kopa nibi idije naa to waye laipẹ yii.

Awọn Kenya, Uganda, Zimbabwe, South Africa, Morocco, Senegal, South Sudan, Democratic Republic of Congo ati awọn to gba wọn lalejo ni wọn kopa ninu idije naa.

Aṣeyọri naa la gbọ pe o ṣafihan akitiyan ati ifarajin Gomina AbdulRahman AbdulRazaq si idagbasoke eto ẹkọ ati awọn ọdọ.

No comments:

Post a Comment

PÍN-IN KÁÀKIRI